Smiley face

Ika JUNE12 Buru Ju 9/11 Lo

Ayafi ti a ba n fi oro sabe ahon so fun ara wa loku, olowo kan ko nife olosi denudenu.

Ife oju lasan ni mekunnu ni si eni to ba rije, erin iyangi si ni mbe loju won ti won ba fojukoju. Ti ko ba ri bee ni, kilode ti olowo ko fe ki olosi naa lowo dani?

Pupo mekunnu ni won si n gbero kolowo subu lule logido laidide nile mo rara. Won a maa so wipe, o se je oun nikan ni?

Bi o tile je wi pe ohun to won bi oju ko fe e si laye, sibesibe a ti reni foju tore ri. Iru won ni won dasa 'mukan-komi-ko-o-mukan-ko-ra-re'.

Opolopo awon mekunnu ni won gba wi pe Moshood Kashimawo Olawale Abiola (Aare Ona-kaka-n-fo ile Yoruba) nife mekunnu denudenu, ti o si setan lati gbon iya nu lara gbogbo teru-tomo(Bi o tile je wi pe awon kan tako ero yii).

Aye o fe o nilu o n darin 'bendalo', ti o ba darin naa tan tani yoo ba o gbe na? Ipolongo ko lo mu opolopo jade dibo lojo Kejila Osu Kefa, Odun 1993, bikose ireti ati igbagbo wi pe ise ati iya aye mekunnu yoo di ohun igbagbe ti 'Emuke' ba wole gege bi
Aare ile Naijeria ni.

A dibo tan ni won ni atanpako taa fi teka doti pupo, boya ti owo wa ba mo ni ibo wa ko ba ti ma di ohun idoti.

Abiola nikan ko ni pakute iku ojiji mu lese latari 'June12' to bo sonu lowo mekunnu, aimoye emi lo pin. Sebi awon taa mo lale daruko bi Toyin Onagoruwa, Kudirat Abiola, Bisoye Tejuosho, lara won la tun ri Suliat Adedeji, Bagauda Kaltho naa o gbeyin ati Pa Alfred Rewane. Iku le Abraham Adesanya naa nigba naa sugbon ohun baba je tele ikun ni o je. Bee aimoye ni won salo seyin odi nigba ibi oro n lo ko ye enikankan mo.

Awon Yoruba bo, won ni ti iya nla ba gbe ni sanle kekere a tun maa gori eni. Sugbon lopo igba, ti iya nla ba gbe ni sanle niila miiran toju ti ateyin wa lo tun le mu ni gun bi ketekete. Oro Abiola dabi afada pakun, ikun lo, ada tun bo sonu.

Ka so wi pe Abiola ko du ipo Aare tabi ki awon asenilori fi ori ese re jin-in, o seese ki oko-owo Abiola ti gba mekunnu lowo ise oun iya to kole to di Mario sile yii ti ko kuro boro. June 12 ko se apeere iyanja lasan bikose okan lara ohun to n sami idorikodo eto oro aje Naijeria.

Opolopo igba ni mo tun maa beere wi pe se lotito ni wi pe omo Ogun kan naa ni Obasanjo ati Abiola? Obasanjo lo odun mejo lori oye, a ko le so ohun pato ti Obasanjo se lati fi nu omije mekunnnu danu ni iranti Abiola. Sibe gbogbo wa loye wi pe iku ti Abiola ku ni oye ti Obasanjo je.

O ti pe ogun odun lonii, emi o ro wi pe o ye ka maa ranti June 12 ka maa banuje mo. Awon agba ni ti ko ba si ohun to se ese, ese kan ki i se lasan.

Ti ko ba je wi pe awon eni ti a ni ko fe ni loju fata senu ni, kilo fe mu oju ti n gun ni tun maa tani bi ata. Eni afeyinti wi pe ko gbani lowo otutu, n se ni won tun tuso moni lara nita gbangba.

O dami loju wi pe 9/11 dun ile Amerika gidi gan-an, nitori wi pe won ko so emi awon omo ilu won nu nikan, Osama Bin Laden tapo si aso ala ogo, iyi, aponle, igbagbo ati ola ile Amerika ni.

Amerika si ko lati darijin ika eniyan, won pa, won si so sinu okun ni. Bo ti le wu ki 9/11 dun Amerika to, ko dun won bi June 12 se ka wa lara si. Nitori ohun ti a padanu ko se e fenu wi jade. Sebi oro to ba koja ekun, n se ni eniyan wo duu bi olundu ni.

Ti mo ba pari apileko mi lai gbe oriyin fun Ibrahim Babangida, a je wi pe mo se oro ku sinu ni.

Mo ki akikanju eni rere fun ise akin to ti gbese ti a ko le gbegbe lailai. Gbadamosi o ku, erinlakatabu mbe ni Minna ti jaye oloba. Mo gbo wi pe eja tutu ni i je lalaale laisi girigiri.

Won ni ti won ba wo aso odi wo inu oja n'Ijebu fi se epe fun enikan. Won ni eni won sepe fun ko ni kije. Bi mi o ri ohun won ti won se l'Akure Oloyemekun, sebi mori posi ti won gbe lOluyole, gbogbo itu ti won pa l'Ekiti to fi mo Eko Adele pata lagbo. Won ni bi Maradona ba gbon bi ifa wi pe iro lo pa.

Olayemi Oniroyin, mi o kere rara gbogbo re pata lo soju mi. Iye mi ko si ra, emi ki i gbagba nnkan boroboro. O dun mi gan-an, mo miri fun iran omo Yoruba, mo si kedun awon eniyan dudu fun iwa dudu owo won ti n gbe won 'leke' nigba gbogbo.


E ku ikale!


@dakewi

Olayemi Olatilewa

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment