Smiley face

Ma Je Oju Namibia -Keshi

"E wi fun olomo ko kilo fun omo re o, nitori wi pe oni o ro" Adari egbe agbaboolu ile Naijeria, Stephen Keshi ti so wi pe eja-n-bakan ko ni eleyii, danda ni ki awon je oju egbe agba boolu Brave Warriors ti Namibia ninu ifesewonse ti o waye lonii yii(12/6/13) ni Nujoma Stadium ni Windhoek.

Ni ana ode yii ti o pe ojo kerin ti egbe agbaboolu Naijeria ti wo ilu Namibia ti won si ti n gbaradi ni kikankikan lati koju Namibia ni Keshi ti n se ileri wi pe awon ko ni pada lowo ofo.

Bi e ko ba gbagbe, egbe Super Eagle din dundu iya fun Namibia ni nnkan bi odun kan seyin ni Calabar ni ibere idije tani-yoo-kopa ninu idije boolu agbaye ti o waye lodun to n bo ni ilu Brazil pelu ami ayo okan si odo(1-0).

E je ka wo awon ilu to wa lori ate "F" ti Naijeria wa ati awon ami won:

Naijeria-Amin Mejo(8), Malawi Amin Mefa(6), Namibia-Amin Merin (4) Kenya- omi(0).
Olayemi Olatilewa
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment