Smiley face

Oniroyin 101

FOTOKOPI

Nje e tile ti gbo nipa awon ti won pe ni 'SAWO-SOGBERI' ri?

Awon ogberi ti won maa n sebi awo loju awon alaimokanmokan. Bee ti ogberi ba foju kan awo gidi iru won a si pada di yeye lasan.

Bi ise orin kiko se sunmo ise iroyin kiko to, sibesibe awon ohun kan wa ti eniyan le segbe nibi ise iroyin ti eniyan kosi gbodo dasa iru e nidi orin kiko.

Aimoye awon ti won pe ara won ni ojulowo oniroyin lo je wi pe atunte ise egbe won ni won n se ti won si n gba orinyin le lori bi igba ti olorin ba n ji orin egbe re ko.

Ti a ba si ni ka woo daradara, ko si ohun to buru ninu ki olorin korin ti won ti ko ri tabi ki akoroyin ko iroyin ti enikan ti te sojude. Ohun to se pataki ni atinuda onikaluku gbodo fi alafo nla sile gege bi ami idanimo ti o gbodo jo ara won.

Aimoye olorin ni a ri lawujo wa ti o je wi pe pupo orin won ni ati gbo ri, sibesibe aye tun un teti gbo orin ti won ko nitori wi pe won fi ona ra se agbekale orin naa, eleyii to mu orin bee dun leti ju ti tele lo.

Pupo iru awon orin wonyii gan-an ni eniyan le ma fe e mo eni to lorin gan-an ni pato nipa ata ati alubosi ti olorin tuntun ti ko wo irufe orin bee eleyii to mu ta sansa leti awon eniyan awujo.

E mi ro wi pe bee gele loye kori ninu ise iroyin sise. Bi o tile je wi pe awon oniroyin maa n ran ara won lowo lati ma je keti di si awon ohun to n lo lowo layika nitori gbogbo wa ko le si nibi ti isele ba ti sele gan-an ni pato. Sugbon eleyii ko fi aye gba oniroyin lati maa jale ise opolo oniroyin egbe re.

Opolopo awon oniroyin ni won maa n se adako iroyin akegbe won eleyii ti o si maa n mu irewesi ba ojulowo oniroyin ati awon eniyan awujo ti won ka tabi gbo orisii patani iroyin kan naa ni eemewa.

Olayemi Oniroyin, mo bu enu ate lu awon ogberi onise opolo lonii. Gege bi oniroyin, ti a ba le so ohun ti awon eniyan awujo ba n se ti ko dara to, kosi ohun to buru ti a ba koju sinu ile ki awon naa si bu enu ate lu ohun ti awa naa n se to kudie kaato.

Sebi awon Yoruba loni ti oju ba n sepin, ka yo ipin loju ka si fi han oju lo dara.

Emi ri yin naa, mo tun n pada si yewu mi.

E ku ikale

@dakewi

Olayemi Olatilewa

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment