Smiley face

Buhari Se Nagode Mokanlelaadorin (71) Fun Awon Omo Naijeria Leyin Ayeye Ojo-Ibi Odun Mokanlelaadorin Re

Ajagunfeyinti Muhammed Buhari ti ranse ikini re si gbogbo omo Nigeria fun bi won se ba yo ayo odun mokanlelaadorin(71) to pe lori erupe ile lana ode yii.

Ojo ketadinlogun osu kejila ni won bi Muhammadu Buhari ni odun 1942.

Oun si ni olori keje to je ni ile Naijeria, nigba to je Olori gege bi Aare ologun lati December 31, 1983 si August 27, 1985.

Leyin igba yii, Ajagunfeyinti Muhammed Buhari ti gbiyanju lati dije ipo Aare ni odun 2003, 2007 ati 2011 eleyii ti gbogbo re jasi pabo.

Iwadii fi ye wa wi pe ara iran Fulani ni Buhari, o si wa lati eya Daura to wa ni Ipinle Katsina.

Iroyin mii to tun jeyo ni wi pe awon kan ti n polongo re ni apa oke oya ile Naijeria gege bi Aare ti yoo dije labe egbe oselu APC.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment