Smiley face

Eemo Wolu: Amotekun Ti Pa Olutoju Re Je Logba Eranko Shanghai To Wa Ni Ilu China

O seni laanu wi pe baba agbalagba eni odun metadinlogota(57) ti oruko re n je Zhou to ye ko ti feyinti ni nnkan bi odun meta seyin ni ogba eranko Shanghai ti pada kan agbako iku ojiji lowo Amotekun to sadeede ko agidi bori bi ponmo funfun.

Baba yii lagbo wi pe o n gbiyanju lati se imototo yara ihamo ile amotekun naa saaju ki won to fun un lounje je, eleyii to pada bo si ibinu eranko ti won pe oruko re ni Yingying.

Gege bi awon alase ogba eranko naa se gbe alaye won kale, won ni awon ko gba wi pe ebi lo mu Yingying seku pa Olutoju re. Won ni o ni lati je nnkan mii eleyii ti iwadii si n lo lowo nipa re.

Ju gbogbo re lo, awon alase ogba eranko yii ti wi pe awon ko ni tori isele naa pa amotekun naa eleyii ti won bi ninu ogba eranko Shanghai ni nnkan bi odun mesan-an seyin nitori wi pe ko wu iru iwa bee ri.

Olayemi Oniroyin, ilu China ni mo ti sare de. Nibi ti amotekun eni odun mesan-an ti seku pa baba agba eni odun metadinlogota. Iroyin ba pari!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment