Leyin faaji opin odun ti oga agba ile ise ifopamo Access Bank, Ogbeni Aig
Imokhuede se lopin ose to koja eleyii to pe olorin ile Amerika, Mariah Carey pelu owo bi igba milionu (200M) ni awon osise ile ise ifowopamo naa ri gege bi inakuna.
Won ni ariya ti won pate kii se fun awon osise banki, won ni oga awon lo n se ariya pelu awon ore lasan ti won si n fi owo banki se faaji ara won.
Ti e ko ba gbagbe, laipe yii ni banki yii da awon osise won bi igba(200) duro lenu ise lai nidi kan pataki.
Awon kan ni boya ko le rowo se iranu lo fi se bee.
Bi o tile je wi pe awon osise banki naa ko foju han, sugbon aridaju wa wi pe inu won ko dun. Won si tun se ileri lati tu awon ohun ikoko nipa oga won ti a gbo wi pe oun naa wa lara awon to n jijadu lati je gomina banki apapo Naijeria (CBN).
Home / Uncategories / "Ko Se Party Fun Wa o, Ara Re Lo Se Party Fun. Igba Milionu (N200M) Lo Si Fi Pe Mariah Carey" Awon Osise Access Bank N Binu Si Oga Won
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment