Smiley face

Onidajo Brian Barker Ti Ran Minta Omo Ilu Ghana Lewon Odun Metadinlogun Ni Ilu London Latari Esun Wi Pe O Fi Itara Ati Owu Jije Gun Iyawo Re Lobe Pa.

Kaadi ikini keresimesi ti Minta Adiddo fi ranse si iyawo re, Akua Agyeman to wa lori beedi nibi ti won ti n toju re ko da iku iyawo re duro nigba ti awon dokita fi idi re mule wi pe igba meedogun otooto ni Minta fi obe gun iyawo re eleyii to fura si wi pe o n ya ale.

"Ololufe mi, darijin mi, ise esu ni. Asise nla gbaa ni mo se. Joo, forijin mi" Kaadi keresimesi alaranbara ti Minta fi ko leta si iyawo re leyin to gun lobe pa.

Iyawo Minta ti pada ku lati bi osu meji seyin to ti n je irora iku ni ile iwosan.

Awon ebi Akua Agyeman ko le pa edun okan won mora. Awon oro bi epe bi epe ni won si ko sinu leta ti won fi ranse si Minta ni ilu London eleyii to te onidajo re naa lowo.

Won ni yato si wi pe Akua Agyeman je olu omo idile awon, oun kan naa ni igi leyin ogba ti awon gbe emi le to je wi pe oun lo n toju gbogbo ebi lapapo.

Won si dupe lowo Minta pelu aseyori 'ise akin' nipa bo se da emi omo won legbodo.

Leyin atotonu awon agbejoro, onidajo Brian Barker QC fi ero re han nipa isele naa.

O ni a ko le so wi pe Minta Adiddo finufido pa iyawo re, Akua Agyeman. O ni ohun to sele waye latari itara, aragbigbona ati owu jije eleyii to mu oko re si iwa wu. Fun idi eleyii, onidajo saanu re nipa fifi ewon odun metadinlogun(17) taa lore pelu ise asekara.

Omo odun mejilelogbon ni Akua to ku, omo meji lo si fi sile saye lo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment