Smiley face

Tani Oserebirin Ti N Gba Owo To Poju Lo Lowolowo Bayii Ni Ile Nigeria?

Sebi awon Yoruba loni oba mewaa, igba mewaa loni ile aye. Enikan o si lo ile aye gbo.

Igba to yi kan Genevieve Nnaji ati Omotola Jolade nigba kan ri ti dabi eni wi pe o ti n yi kan Mercy Johnson bayii.

Gege bi a se gbo, owo ise omobirin ti won bi lojo kejidinlogbon osu kejo odun 1984 ko din ni milionu meji owo naira (N2M) fun ise sinima kan soso to ba fe kopa ni inu re.

Bo se je wi pe oun ni owo re poju laaarin awon irawo osere egbe re, sibesibe awon onise fiimu agbelewo ni Naijeria ati Ghana n wa kiri ni lati je wi pe o foju han ninu ise won.

Olayemi Oniroyin, irawo to n tan yii temi ni. Igba to n dun yii ni ti Mercy Johnson.

Bi o tile je wi pe ilu Eko ni won bi si sugbon omo Okene ni ilu Kogi ni i se.

Too, bo se n lo niyen labala ti fiimu agbelewo ti ile wa.

E ku otutu ti mbe lode yii
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment