Sebi awon agba loni ilu ki i wa laini oba alade. Leyin ti Oba Adebiyi Adesida goke aja, awon afobaje ilu Akure ti pe birikoto lati fi Omooba 'birin Adetutu Adesida Ojei to je beere (akobi lobirin) oba to lo je adele titi won yoo fi yan Oba tuntun.
Gege bi a se gbo, ilu Oba (UK) ni Omooba Adetutu Adesida Ojei ti wale lati wa gori ite baba re. Bakan naa lo si se ileri lati se ojuse re lati mu ilu Akure tesiwaju ati paapa julo lati se iranlowo fun awon afobaje lati yan olori to ye fun gbogbo omo ilu Akure.
Iroyin mii to tun jewo ni bi Oba Ilu Akure ti won yo loye lojosi, Omooba Adesina se n bebe ati pada sori oye.
Omooba Adesina ni won yo loye latari bi o se ko awon janduku lo na olori re, Olori Bolanle mo ile re ti won si da asiidi si lara eleyii ti olori naa ti ku bayii.
Awon kan ni ki won darijin oba naa wi pe asise ni. Ero awon kan tun ni wi pe iru Omooba Adesina ko ye loba ilu Akure.
Kini ero ti yin?
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment