Smiley face

Iroyin Kayeefi: Ki Eniyan Ma Fi Omi Kan Ara Re Fun Ogota Odun

Amoo Hadji Eni Ogorin Odun 
Amoo Hadji eni ogorin odun (80) to je omo ilu Iran ni ile ise iroyin Iran, Iran News Agency (IRNA) ti se afihan re gege bi eniyan to ti to nnkan bi ogota (60) odun seyin to ti fi omi kan ara re.

Gege bi Iran News Agency se so, abule kan ti oruko re n je Dezhgah to wa ni agbegbe Dehram ni Fars ni okunrin yii n gbe.

Baba  agbalagba yii feran ko maa mu awon igbe eran to ti gbe bi igba ti eniyan n mu ikoko taba. A si tun ri gbo wi pe lopo igba ti otutu ba n mu ni maa n da koto bo ori bi awon olokada ti won mbe l'Eko Tinubu ti yoo tun maa fa siga bi mefa po leekan soso.











 Bi o tile je wi pe iroyin ko so fun wa boya Amoo ni arun opolo tabi oni awon agbasodi esin tabi igbagbo kan to le mu maa wu iru iwa bayii, ko si idaniloju wi pe otito ni wi pe eniyan olopolo pipe bi awon eniyan to ku ni.
 
Ti e ba teju mo o lara, e ri wi pe awo ara re ti yibo bi ti igba ti mbe leyin ijapa, oju re ti hunjo bi ti ijimere, eekanna owo re ti ko eje sabe. Awon eniyan agbegbe naa salaye oorun ti n jade lara re bo ti to. Won ni oorun buruku ti n run jade lara re run de orun alakeji. Yato si ikoko taba ti n maa ro igbe eran si, baba naa tun feran ko maa je oku eran ti won gbe sonu sakitan. Won ni to ba yan awon eran naa gbe tan bi lokili ti won je ni ilu Ondo ni maa n ri.
 
 
Olayemi Oniroyin, gege bi oro awon Yoruba ti mo lo lana: Were dun wo loja ni, ko si eni ti n gba a ladura ko ba won bi alagana lomo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment