Smiley face

Ọmọ Ẹgbẹ Agbabọọlu Arsenal To Gbe Ọmọge Lọ Ilé Itura Ti Tọrọ Afọrijin Leyin Ti Asiri Tu

Ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Olivier Giroud ti pada tọrọ aforijin lọwọ iyawo rẹ ati ẹgbẹ agbabọọlu rẹ pelu bo se gbe àlé lọ si ile itura nigba to ku bi wakati diẹ lati bọ sori pápá.

Giroud gbe Celia Kay, eni to n se isẹ oge sise lọ si ile itura Four Seasons to wa  Canary Wharf ni ọjọ keji osu keji odun yii nigba to ku diẹ ki ẹgbẹ agbaboolu Arsenal wáàkò pẹlu Crystal Palace.  


    
 Celia Kay, àlé Olivier Giroud

Olivier Giroud ati iyawo ile re

Arsene Wenger
Bi ọ tilẹ je wi pe Olivier Giroud kọkọ parọ fun ọga rẹ nipa isele naa. Sugbon bayii ti Camera ti pada tu asiri bi ọmọge se jade niyara ile itura ti Giroud wa ti je ki irọ rẹ ja le lori. Oro taa si ni ki baba mọ gbọ, a se baba naa ni o pada pari rẹ.
Celia Kay
Ninu oro Celia Kay, oni bi wakati bi meji ti oun fi wa pelu Olivier Giroud ninu yara, oni ibalopo kankan ko waye laaarin awon mejeeji. 

Kini awon mejeeji wa n se ninu yara ọlọ́yẹ́ fun odindi wakati meji?

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fi iya jẹ Crystal Palace pẹlu ayo meji si òdo ninu ifẹsẹwonsẹ to waye lọjọ naa(2-0) .

 Aworan ti Celia Kay ya ninu yara ile itura naa
 Aworan Olivier Giroud ninu yara ile itura pelu àlè rẹ.
 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment