Ajo EFCC ti wo gomina Ipinle Oyo nigba kan ri, Christopher Alao Akala omo Iya Alaro lo si kootu latari esun jugudujera owo ijoba bi bilionu mokanla abo (N11.5B) owo naira to koje. Owo yii ni won ni Akala koje ni awon igba to wa lori oye gege bi gomina Ipinle Oyo
Gege bi esun ti awon Ajo EFCC tesiwaju adajo, won ni aimoye ise akanse ni Akala gbe jade lai gba awon ona to to ati ona to ye. Eleyii to jasi apapin lai ni isiro to giriki ti N11.5B si se bee poora lojiji.
Akala ti won ko ti pari ejo re lagbo wi pe o ti sare lo pe ejo ko-temi-lorun ni ile ejo to ga ju lo. Sugbon itiju lo ba pada nigba ti Onidajo Monica Dongban-Mensem daa pada si ile ejo ti won ti n gbejo re wi pe ayafi ti won ba da ejo tan ni Akala to leto ati pe ejo kotemilorun si ile ejo giga.
Awon esun bi mokanla ni won ka si Akala lese, Olorun nikan lo si le je ko bo ninu wahala to ko si naa.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment