Smiley face

"Ibaje Eniyan Ko Da Ise Oluwa Duro" - Odunlade Adekola

Awon Yoruba so wi pe iwofa lenu, eniyan le ran enu re ni Kafansa ko kan eniboodi rara. Sugbon sa, awon eniyan buru, aleebu ara eniyan ni won maa n tejumo lati fi se ibaje eniyan kiri.

Awon onibaje Odunlade Adekola tun ti pade senu ise won nipa aheso oro wi pe ogbontarigi akoni osere tiata ti opolopo mo si Sunday Dagboru ko le so geesi ko dan moran pelu bo se ti pada si ile iwe.

Akojopo Olayemi Oniroyin si fi da wa loju wi pe kii se wi pe osere naa ko gbo ohun ti awon onibaje re n so kiri, sebi iwofa lenu. Esi omokunrin naa ko si po rara,'ibaje eniyan ko da ise Oluwa duro'.

Osere to ti bere si ni ko nipa imo Isakoso Okoowo ni Ifafiti ti Ipinle Eko ni won ni ko ti mo awon ofin to de girama ede geesi dojudoju pelu bo se maa n se opolopo asise ninu isoro re.

Won ni eyi si wa lara nnkan ti omokunrin naa fi maa sa fun awon oniroyin fun iforowanilenuwo.

'Ohun to ba wu awon eniyan ni won le so. Se won wa nibe nigba ti mo n sa fun awon oniroyin? Ibaje eniyan ko da ise Oluwa duro" Odunlade

Awon amuludun kii bo lowo enu aye. Igba kan naa ni won ni Yinka Ayefele ko bimo tabi ko le bi omo. Sugbon ohun to daju ni wi pe tosan-toru ni Baba Morayo fi n 'faya', Edumare si n ba fi ere si gbogbo isooru ti n se.

Olayemi Oniroyin, orin Agbajelola Sikiru ni maa fi kadi abala iroyin awon onibaje eniyan fun toni. Ti mo ba ti n ko ni ke e maa ko tele mi. Se e ti setan?

"E soro Ayinde mo niwon
E soro Ayinde mo niwon
Nitori ori o gbodo fo"

O ya e gberin oo...

"E soro Ayinde mo niwon
E soro Ayinde mo niwon
Nitori ori o gbodo fo"

Odabo!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment