Smiley face

Warrior Ku!

Okunrin onijakadi, James Brian Hellwig, ti gbogbo eniyan mo si The
Ultimate Warrior ku ni eni odun merinlelaadota (54).

Ana ode yii la gbo wi pe okunrin naa subu lule ni ilu Arizona nigba to n lo lati wo inu moto re pelu iyawo re.

Won sare gbe okunrin naa lo si ile iwosan sugbon epa o gboro mo, ajanaku sun bi oke.

Lara oro okunrin naa to so gbeyin ni eyi to so ni ojo karun-un osu kerin odun yii nigba ti won fi oruko re sara awon olokiki agbaye. Ohun ti Warrior so ni yii:

"One day everyone must breath his last. And at that time, all that would matter would be what you had done while you were breathing. That's what keeps your legacy living..."

Ki Edumare ba wa te si afefe rere. O digba, Kako-Onikunmekun ti Ilu Amerika!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment