Smiley face

Ajo FIFA Ti Fe Se Idajo Buroda Elehin Samuga-Elehin Aja

Awon Yoruba ni ibi ija lehin wa sugbon bi ti ere boolu ko. Ajo boolu agbaye FIFA yoo se idajo Luis Suarez to je omo agbaboolu Uruguay ni ale oni (26-06-14) latari bo se bu omo ile Italy kan, Chiellini  je ninu ifesewonse ere boolu to gbeyin ni isori D ninu idije boolu agbaye to n lo lowo ni ilu Brazil.

Bi o tile je wi pe oludari ere naa ko sakiyesi iwa ti Buroda Elehin Samuga wu nigba ti idije naa n lo lowo, sugbon ohun ti a gbo ni wi pe o seese ki won fun Luis ni ijiya odun meji lai gun ori papa boolu.

Igba keta ni yii ti Luis yoo maa fehin ja lori papa. O si ti toro aforijin nigba kan wi pe oun ko ni se bee mo. Sugbon gege bi oro awon Yoruba, iwa ata ko yato - boya e gun lodo tabi e lo ninu olo.

Uruguay na Italy ni ami ayo kan si odo eleyii to fun won ni anfaani lati bo si ipele ko-mese-e-yo eleyii ti NIgeria naa ti rari wo.

Olayemi Oniroyin, e je n duro nibi. Nitori mi o ni fe ki sombodi lo bu mi lehin je.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment