Smiley face

Awon Ti Won Mu Iyo Bi Gaari Nitori Ebola Ti Ku Ni Plateau

Latari iroyin eleje ti gbogbo aye n pariwo kiri wi pe eniyan le dena arun Ebola nipa fifi iyo sinu omi mimu ati omi iwe ti ran eniyan meji lo sorun apapandodo bayii ni Ipinle Plateau.

Awon eniyan bi ogun ni won si ti se ara awon lese to je wi pe osibitu ni won wa bayii nibi won ti n gba itoju.

Gege bi iwe iroyin This Day Newspaper se gbe iroyin naa kale, aseju ni awon eniyan naa fi  kun un nipa aimokanmokan won eleyii to pada jasi ijanba fun ago ara won.

Awon eniyan wonyii la gbo wi pe won so iyo di gaari ti won si bere si ni gbemu ki oro to yiwo mo won lowo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment