Smiley face

Awon Omo Ile Iwe O.A.U Ti Bere Sini Se Ara Won Lese Latari Abewo Aare Jonathan Sinu Ogba Ile Iwe Naa.

Ija nla be sile laaarin awon ololufe ati alatako Aare Jonathan ti won je omo ile iwe Obafemi Awolowo University to wa ni Ile Ife.

Ija nla yii lagbo wi pe o waye latari abewo Aare Jonathan sinu ogba ile iwe won nibi ipade kan ti awon agbaagba ile Yoruba ti fonte lu Aare Jonathan gege bi eni ti yoo tun di Aare lodun 2015.

Ija nla to waye lojo Sande to koja yii wa saye latari bi awon akekoo kan se n pe Jonathan ni enirere, olotito, ore ara ilu, eniyan to nife mekunnu denudenu ati eni to ye ka yan sipo lodun 2015 nigba ti awon apa keji so wi pe, awon omo akekoo kan ti gba buredi ati bota lowo Jonathan lo mu won maa korin radaradra nigboro enu won. Won ni ole, odale, apaayan, oloju kokoro, alanikanjopon ni Aare Jonathan, ni ija nla ba be sile bi ogun abele Biafra.

Awon kan tile fe doju oro naa ru, won ni awon omo elegbe okunkun ni won ba ara won ja. Sugbon alukoro awon olopa fun Ipinle Osun, Arabirin Sade Odoro ni ki i se awon omo elegbe okunkun rara. Gege bi oro re, o ni iko meji ti won je omo ile iwe OAU ni won ja latari abewo Aare si ile iwe naa lojo Eti to koja yii.

O kere tan, awon eniyan bi mefa ni won farapa koja bikiafu ninu itaporogan to waye ninu ogba ile iwe O.A.U.

Olayemi Oniroyin loruko mi,
E ku oju lona fun akotun iroyin mii.
Yoo dara fun gbogbo wa o!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment