Lopin ose to koja yii, mo ni anfaani lati joko ba iya mi soro. Iya mi ko joko ti mi fun wakati kan ri laiso itan fun mi. Itan ti iya mi so fun mi loteyi tun je ki n ni oye igbe aye awon eniyan lateyin wa saaju ojo oni. Sebi won ni agba lo nitan, orin lasan lomode le ko lenu.
Baba kan wa ti mo gbonju mo daada, bi o tile je wipe baba naa ti ku bayii. A maa n pe oruko baba naa ni Baba Tubosun. Ore ati kekere lo je si baba to bi mi sugbon o ju baba mi lo lojo ori pupo. Ti ede-aiyede ba fe sele laaarin awon obi mi, baba yii lo maa bu omi tutu si i. Baba Tubosun ni laakaye pupo, mo si feran re nitoori awon akawe oro ti o ma fi gbe alaye re lese. Sebi awon Yoruba naa lo wi pe ohun ti agba ri lori ijoko, bi omode tiro ko le ri lailai.
Iya mi so ohun kan ti baba yii se lojo kan. Won ni baba yii gbera irin-ajo lati ilu Ibadan lo si ilu Eko. Moto baba yii ba taku si aaarin ona masose Ibadan si Eko.
Gege bi iya mi se salaye fun mi, baba yii paaki moto re lo ba lo wo moto ero lati de ilu Eko to n lo. Igba ti baba yii de ilu Eko, lo ba lo si iso awon oni moto tuntun lati lo ra moto tuntun aganran, mesi oloye ti n dan gbirin bi koroshin. (ohun oto lo gbe baba yii lo si ilu Eko, kii se moto gan-an lo ni lokan ati lora tele)
Igba ti baba yii de ilu Ibadan pada leyin ojo bi meta, lo pe mekaliiki re wi pe oko oun wa ni ibi bayii ko lo ba oun tunse ko si gbe pada wale.
Ohun meji lojo mi loju ninu itan yii. A ye rorun nigba naa to je wi pe mekunnu le binu ra oko tuntun laije wi pe o ti n ronu re tele. Oko to taku soju ona masose, ohunkohun ko sonu ninu oko yii fun odindi ojo meta ti won fi wagunle sibi to wa.
Okan mi baje nigba ti mo wo igbe aye ti awon eniyan n gbe lonii. Owo moto ti elomiiran yoo fi wo oko ero lasan won ko ni dani. Laye ode oni, eniyan to ba pe lode won n jigbe anbosibosi moto ti ko ni oluso fun ojo meta.
Aimoiye awon odo ti won jade ile iwe ti ko rise n posi lojoojumo. Enikeni ko bikita nipa ojo ola awon odo ile yii ti won ti so ireti nu.
Joojumo lawon eniyan kigbe ko si ina elentiriki, omi ti gbe nibi won ti n pon, eto aabo ti mehe, kosi ise mo; 'No Vecancy' lo wa, ko si panado ni ile iwosan kato wa so nipa ogun eje atunrase, eko kiko ti deko ati akara(emi o ri ASUU bawi, se Tisa tebi n pa le mefun dani), aimoye awon odo ni won ni ebun to yaayi ti enikeni ko bere ohun ti mbe ninu opolo won.
Eni afehinti bi o ba ye, wiwi nii wi. Kaka ki won bu omi tutu sibi bata ti n ta ara ilu lese, won ni ofin ka fun omo odun meje si mesan-an loyun lo se pataki ju.
Opolopo awon eni a gbokan le ni ko rantii enikankan mo. Awon oloselu ti won bara won sota ni won ti doore pada nitori oselu odun 2015. Awon ti n be lori oye ko ti je eyi ti won n je tan, gbogbo won pata ni won tun du oselu odun ti ko ti de.
Olayemi Oniroyin, maa ma tesiwju ninu alaye mi laipe. Sugbon kini kan lo wu mi ki n beere lowo yin; Igbawo wo gan-an ni iponju ati oshi fe dopin ni ilu wa?
0 comments:
Post a Comment