Aare Goodluck ti fesun kan egbe APC wi pe won ko ni erogba rere kankan fun ara ilu ju lati gba ijoba apapo lo lowo PDP lo. Kosi eni to tako oye Aare nipa erogba awon egbe tuntun APC ti won dasile yii.
O ti pe ti Tinubu ti n sota egbe PDP, Muhammed Buhari o si ba won rerin ri. Ilu kobaje-kobaje fegbe PDP ni gbogbo isomogbe egbe oselu toku n lu lojoojumo.
Bi o tile je wi pe isejoba ti won n du mo ara won lowo yii ki i se lati se ijoba le ebi won bikose lori mekunnu ti won fi ebi pa lojoojumo lo. Awon mekunnu o si bikita iru egbe yowu ko wa loye, ohun ti won n beere ni ijoba ti o ba won tan ise ati iya aye won tan patapata.
Awon eniyan n wa ijoba ti o se ileri ti o si mu ileri won se. Opolopo awon omo won to jiya kawe ni won n gbadura ki Eduamre fun won nise alalubarika ti o mu won gbagbe gbogbo ilakaka ati ekun ti won ti sun seyin.
Fun bi odun bi mejo ti Olusegun Obasanjo ti o je omo egbe PDP fi wa loye, aimoye igba lo se ileri ina elentiriki ti ko ni seju sugbon ko mu ileri re naa se. Goodluck naa ti dan enu fun wa, ko si dabi eni wi pe oun ni ''olugbala'' ti a n reti.
Olayemi Oniroyin, emi kii se oloselu. Ohun to ba si wu onikaluku lo le ro nipa eni ti mo je. Sugbon emi pinnu lati duro lori otito ati ero okan mi ti mo gbagbo. Ohun kan lo da mi loju, egbe PDP kuna. Aimoye ona ni won si ti gba tu awon eniyan je bi isu.
Bi awon ara ilu ba wa ni oro PDP su awon(eleyii ti koti si aridaju) latari ijakule ti won ti ri. Sibesibe, awon eto idibo to waye seyin ti fi ye wa wi pe awon eniyan ko fi taratara tele egbe mo, eniyan ire ti o saanu mekunnu ni won wa. Eleyii si wa lara nnkan ti awon eniyan fi dibo fun Goodluck Jonathan.
Gbogbo bi Goodluck se dannu fun wa wi pe mekunnu ni baba oun, ati wi pe iya oun gan-an kola-kosagbe nii se. To si n wi pe eni moju Ogun ni i pabi nire, eni iya ti je ri lo le toju mekunnu. Sebi eleyii lomu gbogbo ara lu fon sigboro ti won si teka si bi to ye.
Ni bayii, ile ti mo, a si ti rile omi. Awon Yoruba bo, won ni atannido ko le tan ni do ju eekan lo. Aimoye igba ni Egbe PDP fi san wa mole. O si ye ki gbogbo wa ka ti gbon ninuleyin.
Ajagunfehiti Muhammed Buhari ni mo gbo to wi pe ti egbe APC ba fa oun kale lati dije aare wi pe oun setan ati jise. E ba mi so fun Buhari wi pe bi tie ko la n so. Bi eniyan o tile je opolo, o ye ki eniyan je eyi to leyin. Ki Bola Tinubu ma si lero wi pe bi oun ba gbe apoti ipo aare labe egbe APC boya oun le tibe jeun soke. Awon ala ti ko le se rara ni.
Awon eniyan o dibo fun egbe mo, eniyan rere olooto ni won wa. Iya ati osi ti po ju ni ile yii. Naijeria kii se ilu elebi, awon olori won ni won mu ebi pa ara ilu. Ilu Naijeria kii se ilu otosi, awon olori ni won fi osi ta awon ara ilu. Ilu Naijeria kii se ilu ekun, awon olori ibe ni won fi ise ibi owo won pa idunnu ati ayo ilu naa.
Bi egbe APC ko ba le fun wa ni eni rere ti ale fokan tan. Eniyan ti o soro ti o si ri bee, eni ti o se olooto si mekunnu, yato si eni ti a dibo fun tan ti o maa fi iya je mekun. E wi fun won wi pe bi won ba darin iro oun eke, awa o ni ba won gbe iru orin bee lailai.
Ibeere kan pere lo wu mi ki n beere:
Taani Eni Naa Ti Yoo Dije Aare Labe Asia Egbe APC?

0 comments:
Post a Comment