Awon Yoruba ni eti oba nile eti oba loko eniyan ni i je bee. Olori egbe agbaboolu Super Eagles, Stephen Kesh ti fi oruko awon agbaboolu bi ogbon (30) ti n ko lo si ilu Brazil ranse si ajo NFF. Awon oniroyin gbiyanju lati je ki olukoni naa daruko awon eniyan ti o fi oruko won ranse sugbon o ko jale. Gege bi a se gbo, ninu awon eniyan bi ogbon yii ni yoo ti maa yan awon ogbontarigi elese ayo mokanla(11) ti won yoo maa da ilu Brazil ru gburugburu nibi idije boolu agbaye ti yoo bere ninu osu kefa odun yii.
Eni a n gbe iyawo bo wa ba, awon Yoruba ni kii gbe ori iganna woran.
E ku oju lona!

0 comments:
Post a Comment