Smiley face

Won Fi Wheelbarrow Gbe Odindi Ile Alaja-Meje

Airin jina lairi abuke okere. Ti eniyan ba de Belgium, yoo ri ibi won ti n jeun papo mo abo ounje.

Se e fe gbo tuntun? Emi ti ri ibi ti won ti n fi fufu funfun je gala ti won fi epo pupa din.

Emi ti ri oloyun ti oyun jabo lara re ti ko si mo. Igba to dele ni oko re n beere wi pe oyun ikun re n ko. Igba naa lo to fura wi pe oun ti so oyun ikun oun nu sona. Lo ba sara pada wa lo.

Kini awa ko ti ri ri? Sio!

Ojo kan ni mo n wa iroyin kiri ladugbo kan. Omokekere kan ba jabo lati oju window to wa lori ile alajameta. Isele naa se mi ni kayeefi pupo.

Bawo ni omo osu bi meta ti ko ti le ra debi wi pe yoo rin se fe jabo?

Se e mo awon faanu nlanla to maa n wa ni soosi ati mosalaasi? Iru faanu yii lo wa ni yara iya omode yii.

Awon NEPA ti mu ina lo tele, bi awon NEPA se muna de bayii ni faanu bere si ni sise. Kosi si enibodi ninu yara ni akoko naa a fi omode yii nikan.

Faanu ba fe omo danu lati ori beedi sita.

Kini awa ko ti ri ri? Sio!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment