Sebi omo ti eya ba bi, eya ni i jo. Iran ogidan kan ki i
jeran ojokeji. Seun Kuti ni yii, okan ninu awon omo Baba 70. A ti ojo ti
omo naa ti wo ilu Sweden ni gbogbo awon onifaaji alafe ko ti sunle mo.
Seun ni won fe ri, orin re ni won fe jo si.
Inu awon
ololufe orin Baba re ni Sweden dun to bee gee to je wi pe won gba wi pe
Fela Anikulapo gan-angan lo n korin kii se Seun rara. Sebi ola abata ni i
modo san, ola baba omo ni i mu omo yan fanda.
Awon oro
iwuri yii lati enu awon ololufe baba re je bi koriya fun-un eleyii to mu
oun naa fi swagger kun swagger lagbo ariya pelu bi ode orin re se n
tesiwaju kaakiri gbogbo ilu Sweden.
"Aye n fe mi ni Sweden. Won fe mi loju, won femi nimu (pelu ariwo lo fi n soro). Boya ni maa pada wa le mo (O bu serin). Ori baba mi ko pada leyin mi. Orisa merindinlogun ile Adulawo wa leyin mi." Die ninu oro Seun Kuti pelu awon oniroyin Nigeria lati ori foonu.
Ile ni adiye
funfun ko ti niyi, to ba degboro aye; irawo nla ni. Olorun nikan lo mo
iru etutu ebo ti bobo naa gbe ko to wo Sweden. Atomode atagbalagba ni
won sare tele leyin kiri bi eni wi pe won o ri olorin ri. Ka ma paro,
Sweden dun fun omo Anikulapo Kuti.
0 comments:
Post a Comment