Lana la kede nipa baalu kan to ja bo loju orun sinu odo kan ni ilu Taiwan.
Afikun iroyin ti a gbo ni wi pe pupo awon eniyan inu baalu naa lo je awon arin irin ajo-afe omo ilu China.
Baalu TransAsia Airways to ko awon eniyan bi metalelaadota (53) ni awon eniyan bi mokanlogbon (31) segbe sinu re. Awon eniyan bi meedogun (15) lori ko yo nigba ti awon eniyan bi mejila (12) di awati.
Baalu yii la gbo wi pe o pada wa sile ni kete to gbera ni papako ofurufu Taipei.
Ki Olorun Oba ba tu idile awon ti isele naa se si ninu. Amin
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment