Smiley face

Ijebu Fi Owo Dollar Se Alejo Lojo Ayeye Ojo Ibi Awujale Ni Ijebu Ode

To ba je nibi ka fi owo sariya, gbogbo aye ni won so wi pe ariya Ijebu maa n ki bi isale ogi. Ki enikeni ma si fomo Ijebu sere, awon Ijebu gbayi won gbeye lojo ti Oba Sikiru Kayode Adetona, Awujale ti gbogbo Ijebu se ayeye ogorin (80) odun laye.



Olayemi Oniroyin, Olowo Eko ni mo ba lo, Oba Rilwan Akiolu. Igba ti mo debe ni mo pade Oosa ilu Oyo, Alaafin Lamide Adeyemi. Ibi awon alagbara wa ni mo joko si, mo ranti wi pe mo se 'Inakhuana Inagejiah' si ajagunfehinti Muhammed Buhari. Mo ba Gbenga Daniel lowo mo si se 'double tuale' fun Asiwaju Bola Tinubu.

Awon eniyan sadura fun Awujale, won ni ogorin(80) odun to pe bi igba to pe odun merin lasan ni. Aimoye ebun ni won fi ta Oba Sikiru lore lati Ile yii ati loke okun. Awon ti ko le wa gan-an ti fi oko ajagbe gbe isakole wa fun 'Baba 80.'

Adura mi ni wi pe ki Oba gbo bi Olugbongbotigbo to fi omo oolu se onde sorun, onde ohun yo titi o si dokini. Ase.

Ojo kewaa, osu karun-un ni ayeye naa waye ni Ijebu Ode.

Gongo So!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment