Smiley face

Asiri iwosan ibilẹ fun oyun ìju (fibroid) lai se isẹ abẹ

Image result for fibroid
Oyun Iju (Fibroid)
Ọ̀kan  nínú àwọn ololufẹ Olayẹmi Oniroyin ni wọn kọwe ransẹ si wa lati ba wọn tọpinpin nípa iwosan fun oyun ìju ti awon oloyinbo n pe ni “fibroid”.
Abajade alaye mi si ni yii:


 Oyun iju ki i jẹ ki oyun ọmọ gidi duro lara obirin, orisirsi nnkan lo si le sokunfa iju (fibroid). 

Sugbon gẹgẹ bi abajade Olayemi Oniroyin lọwọ awon àgbàlagbà, ohunkohun yoowu to le sokunfa ìju (Fibroid), iwosan rẹ naa ni ẹyìn ti ko ti i pọn (unripe palm kernel).
Image result for unripe palm kernel
Unripe palm kernel and ripe palm karnel

Lílò: Bi obirin ba ni ìju (Fibroid), ki iru obirin bẹẹ gbiyanju lati maa jẹ ẹyìn ti ko ti pọn (unripe palm kernel) bi ẹyọ ogún si mẹẹdogun (20- 25) lọjọ kan (in a day) fun osu kan pere (a month).

Take (chew) 25 units of unripe palm kernels in a day for 30 days 

Èpo ẹ̀yìn rẹ lasan ni eniyan yoo jẹ. Asiko to si dara ju lati jẹ ẹ ni ti eniyan ba jẹun alẹ tan ki ẹ to sun.
Image result for unripe palm kernel
Unripe palm kernel
Ni agbara Olorun, ti iju (fibroid) naa ba ti dagba, obirin naa yoo bi iju naa bi ọmọ danu. Ti ko ba ti dagba, yoo ya danu mọgbẹ ni. Alaafia yoo si deba iru obirin naa lati lóyún ọmọ gidi.

Akiyesi pataki: Gege bi mo ti maa n so, emi ki i se dokita, isẹ iroyin nise mi; iwadii ati itopinpin si ni bárakú      fun mi. Olorun oba oluwosan, yoo se iwosan fun gbogbo alailera pata. Amin.

 Fun awon atejade mii nipa eto ilera, e wa SIBI



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

2 comments: