Aare ile Nigeria, Goodluck Ebele Jonathan, eni ti awon agbaagba ile Yoruba pelu atileyin Ooni Ile Ife ti fonte lu gege bi Aare odun 2015 ti ko leta ranse si ile igbimo asofin agba latari ero ati igbiyanju won lati yo Aare loye bi eni yo jiga.
Gege bi oro Aare Jonathan, " Nje o ye ki awon asofin ile Nigeria tun maa pete a ti yo mi loye pelu laasigbo ti n koju ile Nigeria? Igba isoro la wa yii, o si ye ki gbogbo eka isejoba sowopo lati bori isoro awon agbesunmomi ati oro aje to denu kole."
Sugbon gege bi oro Senator Alkali Jajere, eni to siwaju eto ati yo Aare Goodluck Jonathan loye, okunrin naa fi eebo da esi pada nigba to n ba awon oniroyin soro. O ni "No Going Back".
"Eyi tun mo si wi pe Yekinni kan ko le ye ero awon lati yo Aare Jonathan loye. Ohun to daju ni wi pe Aare ko koju osuwon lati tesiwaju lati maa dari Nigeria."
Gege bi oro re, o ni gbogbo eto ti to, awon omo ile igbimo bi metalelogota (63) ni won si ti fowo si aba naa. O ni ojo kefa osu kejila odun (Dec 6) yii ni awon yoo te esun iwe abadofin naa si iwaju ile nigba ti ile igbimo asoju sofin yoo maa gba eda iwe kan naa fun ayewo.
Home / Uncategories / Aare Jonathan Ko Leta Sile Igbimo Asofin Agba: "Mo Ro Wi Pe Ise Yin Ko Kayin Lara"
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment