Smiley face

Idi Pataki Ti Mo Fi Fe Dibo Fun Odaju, Oninu Lile, Alakatakiti Esin Ti Won Pe Ni Muhammadu Buhari

Kini idi pataki ti mo fi n tele Buhari na? Kilode ti mo fi pinnu lati dibo mi fun odaju, alakatakiti esin, apaayan, oninu lile ati eleyameya eniyan?

Se ori mi pe sa? Ti ori mi ba pe, kilode ti mo fi n polongo Buhari? Sebi bi omode o batan, dandan ni ko ba aroba; aroba si ni baba itan.

Bi mi o ti e ti gbon daada lodun 1983 ti Muhammodu Buhari gori isakoso Nigeria leyin ti won dite gba ijoba lowo Shehu Shagari, sebi mo ri akosile orisirisi ka, bakan naa ni eti mi o sidi si gbogbo iroyin ti n jade lotun losi.
Arise larika, arika ni baba iregun; ohun taa ba se naa laa pada bo wa ba.

Aimoye nnkan ni won so, won ni n se ni awon soja mo n na tomode tagba loju titi bi ewure ati wi pe aimoye awon eniyan ni Buhari ran lo sewon lai menuba awon to seku pa danu lona aito.

Bi mo ba wa pinnu lati tele Buhari pelu gbogbo aida re, o ni lati je wi pe o ni ohun taja ri to fi n gbo. Bi ko ba si nidi obirin ko ni je Kumolu.

Boya idi pata ti mo fi fe Buhari ni wi pe Jonathan ko kun oju osuwon lati je Aare Nigeria.

Mo fe Buhari nitori wi pe mo ti so ireti nu ninu Aare Jonathan.

Mo setan lati dibo fun Buhari, kii se wi pe iwa ire re lo daa to bee, bikose wi pe iye awon eniyan ti Boko Haram n pa labe isejoba Jonathan n ba mi lokan je.

Awon ole, alatenuje, okanjua, madaru, asewo, odale ni Jonathan ko mora ninu isejoba re bee ko si ri ohun to buru ninu isesi gbogbo won pata.

Mo setan lati dibo fun Buhari boya nitori wi pe ko si aabo fun ara ilu labe isejoba Jonathan mo.

Awon omo Chibok niroyin gbe wi pe won jigbe salo, aimoye ni Boko Haram ko pamo tenikan o gbo.

Ki n to dake e je ka wo okan ninu awon alaye Femi Fani-Kayode nipa Aare Jonathan ko to di wi pe Aare ki ori re mabe.

"As I wrote in another contribution almost one month ago,

"the problem that we have is the President himself- a President who prides himself on his own weakness and incompetence and whose love of false prophets and strange women knows no bounds and has no end.

A President who is as confused and as clueless as the comic character called Chancey Gardner in the celebrated 1970's Peter Seller's Hollywood blockbuster titled "Being There".

A President who does not understand the meaning of the word "class" or "honesty" and who breaks his own word consistently.

A President who has abdicated his responsibilities, destroyed his own political party, divided his own country, alienated his own friends, humiliated his own mentor, abandoned his own people, brought ridicule to his own faith, cowers before his own officials, betrays his own governors, scorns the international community and BREAKS HIS SOLEMN OATH TO PROTECT AND DEFEND THE NIGERIAN PEOPLE.

A President who does not even have the nerve or the guts to call to order any of the numerous Jezebels that control him.

He is the problem we have in our country today and until he resigns, is impeached or is voted out of power nothing will change and Nigeria will continue to go from bad to worse. That is what you get when you vote for a man who never wore shoes to school'."

Mo setan lati dibo fun Buhari, mo setan lati dibo fun eni ti mi o fe nitori eni mo fe dami ninu awon ileri to se.

Bi ohun gbogbo ti won tile so nipa Buhari ba ri bee looto, mo mo wi pe ko le buru tayo akoko ta n lo lowolowo bayii.

Ojoojumo ni owo Naira n ja wale.
Jojoojumo ni ado oloro dun.
Gbogbo igba ni won ko owo ile wa salo sokeere.
Riba ati iwa jegudujera si n peleke sii.

Yato si eyi, Jonathan tun gbiyanju lati ma gbe ijoba sile nipa dida gbogbo ogbon lati jawe olubori.

Ojo kejidinlogbon osu keta lojo idajo, o si damiloju wi pe dandan ni ki otito leke.

Ki Oluwa bukun Naija ilu mi.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment