Smiley face

Iwe Iroyin Daily Times Ni Rotimi Amaechi 'Finger' Iyawo Jonathan

'Itafaseyin' ninu litiraso ede Yoruba je sise afihan ohun to ti koja seyin lati tan imole si ohun to n sele lowolowo ninu ere onise tabi dirama, o si le je fiimu agbelewo ede Yoruba.

Bi o tile je wi pe eto ipolongo idibo ti koja, sugbon mo pinnu lati tafaseyin (flashback) lati se afihan akole apenilerin kan ninu awon koko iwe iroyin to ti koja.

Okan ninu awon eto ipolongo egbe APC to waye ni Ipinle Rivers, eleyii to je Ipinle iyawo Aare ile Nigeria nigba kan ri, Patience Jonathan ni ija nla kan ti gbe waye nibi ti won ti n yinbon lakolako nigbagede eto ipolongo naa.

Gomina Ipinle naa nigba naa, Rotimi Amaechi, eni to tun je alaga eto ipolongo fun Aare Muhammadu Buhari nigba eto idibo odun 2015 to waye, di ebi isele naa ru Iyawo Aare nigba naa wi pe oun lo ran awon janduku naa wa lati wa da agbo APC ru.

Ede je ohun to gbooro gan-an, idi ni yii to fi je wi pe awon onkowe gbodo sora gidigidi nigba ti won ba n se amulo ede ninu gbolohun.

Orisiirisii oro kan soso le ni tayo itunmo kan tabi meji. Idi niyii ti onkowe gbodo ri aridaju awon itunmo ti gbolohun tabi oro ni ko to jade sita.

Bi o tile je wi pe akoroyin naa n so wi pe Amaechi di ebi isele naa ru Patience nipa nina ika abuku sii. Sugbon itunmo to yato ni awon eniyan bere si ni fun akole to so wi pe, "Amaechi fingers Patience".

Inu awe la wa yii, mi o ni fe soro ju. Sugbon ojokijo ti mo ba foju mi kan Chibuike Rotimi Amaechi, maa bere idi to fi feran lati maa finger arugbo nibi ti awon omoge gbe po bi yanrin eti okun.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment