Smiley face

Kini ijoba n se nipa awon ti n se ayederu?

Iroyin yii kii se tuntun, yoo si ti to bi osu kan o le die ti asiri awon to n se ayederu elerindodo Coca Cola ti jade. Sugbon iru awon iroyin bayii, a kan maa n gbo naa ni. To ba ya, ategun yoo fe koja lori won, a ko si ni gbo ohunkohun nipa re mo. 


Ibeere ti Olayemi Oniroyin n beere ni wi pe, iru ijiya wo ni won se fun awon ti won se iru ise bayii? Kini ijoba n se lati dekun ayederu nisise lawujo wa? Aimoye ayederu oogun oyinbo lo kungboro to n seku pa awon mekunnu ni joojumo. 

Bakan naa lomo se sori ti a ba n so nipa fiimu agbelewo. Gbogbo igba ni awon to n se fiimu tiata n kigbe wi pe ere ise owo awon, awon ika eniyan lo n gbadun re. Bawo ni orileede se fe tesiwaju ti a ba n gbe iru igbe aye bayii? 

Kini e lero wi pe ijoba lese? Iru ijiya wo ni ijoba le gbe kale fun awon ti won ba ba  nidi iru ise buruku yii?

Olayemi Oniroyin maa dake nibi naa. Sugbon tewure ba bojuweyin, dandan ni yoo bu epe felepe.
E le kan nipa ero awon eniyan NIBI
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment