Smiley face

Wunmi ku nipinle Ondo nigba to fe seyun



*Owo babalawo lo ti gba oogun oyun sise naa
Wunmi Agbeluyi
Bi o ti wu ki eniyan daju bi ose to, ti eni naa ba ribi ti Wunmi Agbeluyi, omobirin eni ogun odun (20), ti n japoro iku nipase inu rirun leyin ti babalawo fun loogun lati fi seyun, onitoun yoo bu omi loju surusuru bi agbara ojo ti n wo yan-anrin geerege. A-gbo-sogba-nu ni iku Wunmi, omo ile eko Rufus Giwa Polytechnic to kale siluu Owo, je fun awon eniyan ti won gbe ni Ijare to kale si Ijoba Ibile Ifedore to wa ni ipinle Ondo.


Gege bi alaye to te OLAYEMI ONIROYIN lowo, baba to bi Wunmi je babalawo-onisegun to danto, oun kan naa si loga to ko afesona Wunmi nise isegun tewe-tegbo. Sugbon awon akoko ti afesona re n kose lowo yii, baba Wunmi ko fowo si ajosepo omo re pelu omo ikose re rara. Sugbon kete ti baba Wunmi rewaleasa ni ife bere laaarin awon mejeeji.

Sugbon nigba to ya, leyin igba ti owo ti wewo daada laaarin Wunmi ati afesona re, ti “nnkan todun” si ti sele laaarin awon mejeeji ni Wunmi se akiyesi wi pe oyun ti duro lara oun. Oko afesona, eni to ti mo bi won se n fi eeji kun eeta ba gbe oogun kan fun Wunmi wi pe ko gbemu. O ni oogun naa yoo mu ki oyun re naa wale nirowo-rose; niwon igba to ti je wi pe awon mejeeji ko ti setan lati di baba ati iya omo.

Laiforogun, leyin ojo meloo kan ti Wunmi ti da nnkan je ninu bere si ni run. Inu naa run debi wi pe ko loju orun mo, ko le duro, bee si ni ko le bere. Sebi won ni iduro o si, ibere kosi feni to gbodo mi. Oko afesona re sare gbe lo sile iwosan kan legbe ile, ile iwosan naa ni won ti fi tipatipa fo oyun inu re naa danu patapata.  

Sugbon kaka ko san lara iya aje, abo lo tun un fi gbogbo omo inu re bi, eye ba tun un yilu eye. Inira ati inu rirun ko fi Wunmi sile leyin ti won ba fo oyun inu re tan. Kaka bee, inira ohun tun goke sii ni. Igba ti agbara osibitu naa ko ka mo ni won taari re lo si osibitu ijoba ipinle fun itoju to peye. Ile iwosan ijoba ipinle ti won gbe Wunmi naa lo lo pada dake si.


Gege bi iwadii OLAYEMI ONIROYIN, omo orukan ni Wunmi, baba ati iya re ti ku. Igba ti oro naa sele, Wunmi ko jewo ohun ti n se e nipato fun egbon re. Ore Wunmi kan ti n je Omololu lo sare lo kesi egbon Wunmi nigba ti wahala naa ti gbe won de osibitu ijoba ipinle.

Ohun ti a tun gbo ni wi pe oko afesona Wunmi ko jewo fun awon dokita nipa ohun to n se Wunmi nipato ati orisii ogun to fun un mu.

“Ojulumo kan lo wa fi to mi leti wi pe won ti gbe aburo mi lo si osibitu, ati wi pe, ipo to wa ko dara rara. Mo sara janajana de osibitu, igba ti maa debe, inu inira ni mo ba Wunmi ti n pariwo inu rirun. Bakan naa lo ko lati gba abere atoogun ti awon dokita ni ki won fun un.

“Ni akoko ti a fi wa ni osibitu, Wunmi ko jewo wulewule oogun ti afesona re fun wi pe ko mu fun mi. Leyin eyi lo ku, a si lo sin si Ijare. Leyin ti a sin ni asiri oro tu si wa lowo nigba ti awon eniyan tomiwa lati fun mi ni labare,” Funke to je egbon Wunmi se lalaye bee.

 Awon eniyan toro naa soju won ni ile iwosan adani ti oko afesona re koko gbe lo, nibi won ti ba fo oyun naa jade ki won to gbe lo si osibitu ti ijoba, niwon salaye gbogbo ohun to sele pata fun egbon Wunmi

Egbon Wunmi ati awon ebi yoku gbe ejo naa lo siwaju ori ade, Olujare ti Ijare lati ba won dasi oro naa. Ori ade gba won nimoran lati lo fejo naa sun ni ago olopaa.

Leyin ifisun yii ni awon olopaa wa mu babalawo ati dokita to ba won fo oyun naa danu, ti won si lo fi won pamo sinu gbaga.

Nibayii, awon ebi oloogbe ti n rawo ebe si ijoba, awon alase ati gbogbo eni toro naa kan lati dide iranlowo ki idajo ododo le waye.

“Abigbeyin ebi wa ni Wunmi, ibanuje nla ni iku re je fun idile wa, a si be awon alase lati je ki idajo ododo sele lori awon asebaje ti won won ran Wunmi nibi ti ko ti setan lati lo,” Funke fi kun oro re bee.

Gege bi ohun ti a gbo lati Ogbeni Femi Joseph, asoju ile ise olopaa ipinle naa, ni wi pe, iwadii si n lo lowo lati mo gbogbo wulewule isele naa. Bakan naa ni won se ileri lati kede ababo won leyin iwadii to gbepon.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment