Smiley face

Arambara aṣọ oge tuntun lọrun awọn ọlọpaa SARS



*“Sebi ba a ṣe rin la a koni” Kọmisanna ọlọpaa Eko
*Arase da awon ayederu olopaa lagara

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii ti paarọ aṣọ iṣẹ awọn ọlọpaa ẹka ti n gbogun ti idaran ti a mọ si SARS. Igbesẹ tuntun yii ni wọn gbe lati kasẹ awọn ayederu ọlọpaa SARS nilẹ ati irisi iwọṣọ awọn ọlọpaa naa seyin eleyii ti won ni ko dara to.


Aṣọ awọn SARS tuntun yii lo ni awọn akanṣe nomba onikoodu pẹlu orukọ ipinlẹ ti ọkọọkan wọn yoo ti ma ṣiṣẹ.  Igbesẹ  tuntun nipa pipaarọ aṣọ iṣẹ wọnyi lo jẹ lara atunṣe ati eto tuntun ti ọga ọlọpaa ile yii patapata, Solomon Arase, gbe kalẹ.

Gẹgẹ bi kọmisanna awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, Fatai Owoseni, se n se e lalaye nigba ti won se afihan awon aṣọ iṣẹ tuntun naa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, o ni aimoye ẹgbin ati abuku n ileese ọlọpaa ti ri sẹyin lati ara awọn SARS nipasẹ aṣọ wọn.

“Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa patapata, Solomon Arase, ni a ba yin lawo pẹlu arojinlẹ ọgbọn lati e igbejade aṣọ iṣẹ tuntun naa fun awọn ọlọpaa SARS. Ọna ara ni wọn gba ṣe awọn aṣọ naa eleyii ti yoo jẹ ko rọrun fun awon eniyan awujọ lati da ojulowo SARS mọ.
Ju gbogbo re lọ, aṣọ ọlọpaa ko ye ko jẹ ka-saa-ri-nnkan-wọ lasan lo yẹ ko jẹ. Sebi awọn agba naa ni wọn wi pe, ba a ṣe rin la a koni. Awon nnkan wọnyi ni ileeṣẹ ọlọpaa ro papọ ki wọn to ṣe aṣọ iṣẹ tuntun naa fun awọn ọlọpaa SARS,” Ọgbẹni Owoseni ṣe alaye naa bẹẹ.

Ọgbẹni Owoseni ko dakẹ sibẹ, komisanna tun fi kun un wi pe, lati akoko yii lọ, ẹnikẹni to ba kan wọṣọ dudu ti n pe ara rẹ ni SARS kii ṣe ojulowo. O si rọ awon eniyan awujọ lati fa iru ẹni bẹẹ le awọn ọlọpaa lọwọ ni kiakia nitori wi pe ọdaran pombele ni.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment