Smiley face

Ayẹyẹ ọjọ ibi Amosun kọyọyọ l’Ẹgba Alake



*Wale Dada ni ojiṣẹ Ọlọrun ni gomina
Amosun ati awon komisanna re
"Ohun idunnu julọ ati ẹkunrẹrẹ ayọ ni imuṣẹ awọn ileri wa si awọn eniyan awujọ. Eleyii ti yoo ni ipa to jọju ninu igbe aye wọn, ti yoo si mu igba rọrun fun tẹru-tọmọ"  Eyi  ni ọkan lara awọn ọrọ iwuri ti gomina Ibikunle Amosun fi side idupẹ rẹ nigba ti awọn eniyan wa ba yọ ayọ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgọta (58) to ko lọjọ Aje to kọja yii (25/1/15). 


Aimọye awọn eniyan ni wọn pejọ si June 12 Cultural Centre, Kutọ to wa ni Abeokuta lati wa ba gomina yọ. Gbogbo wọn naa ni wọn si n gbe sadankata fun aseyọ iṣẹ takuntakun Amosun nipinlẹ Ogun eleyii ti ko lẹgbẹ.

Wayio, ogbontarigi sọrọsọrọ ori rẹdio ati telifisan, Adewale Dada Thegood ti ṣe alaye gomina Amosun gẹgẹ bi ojiṣẹ kan pataki ti Ọlọrun ran wa saye lati fi itura si igbe aye awọn mẹkunnu. Sọrọsọrọ ori rẹdio ti wọn fi ami ẹyẹ Dokita da lọla niluu Ibadan, ni awọn iṣẹ akanṣe idagbasoke Amosun ṣẹ afihan rẹ gẹgẹ bi olotitọ ti kii yẹ adẹhun rẹ to ba ṣe.

Amosun ko sai dupẹ lọwọ Ọlọrun fun idasi ati alaafia. Bakan naa lo dupẹ lọwọ ẹbi ati awọn alajọṣiṣẹ pọ rẹ fun atilẹyin wọn ati ifọmọniyan ṣe.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment