Smiley face

Ẹgbẹrun mẹrin ekute ti kọja sọrun niluu Eko




Ẹgbẹ oṣiṣẹ alaabo ilera ayika, Environmental Health Officers Association of Nigeria, ẹka ti ilu Eko, ti kede wi pe, awọn ekute bi ẹgbẹrun mẹrin ati irinwo (4400) ni awọn ti ran lọ sọrun aremabọ bayii. Eleyii ni wọn se ni awọn ọja bi mẹfa ti akanse eto ti wọn gbe kalẹ lati kasẹ awon ekute nile ti gbe waye. 


Aar ẹgbẹ naa, Samuel Akingbehin, ni akanse eto ikasẹnilẹ ekute laaarin Eko, eleyii to wa ni ibamu a ti gbogun ti iba Lassa, lo waye ni oja Onigongbo, Oshodi, Oke-Odo, Ikotun Idanwo, Ojuwoye ati Mile 12 ti gbogbo won kale si ipinlẹ Eko Gomina Akinwunmi Ambode.

"Akanse eto ikasẹnilẹ ekute yii la gbe kalẹ lati le ajakalẹ arun iba Lassa jina ni awujọ wa, eleyii ti orisii eku Lassa ọlọyan rẹpẹtẹ n gbe e kiri,” Ọgbeni  Akingbehin se alaye naa bẹẹ.


Arun iba Lassa ni o ti seku pa ida aadọrin o le (76%) ninu awọn eniyan ti ijamba naa ti kọlu. Nigba ti awọn isẹlẹ iba Lassa bi igba (200) ti fojuhan ni awon ipinle bi metadinlogun (17) ni orileede Naijiria.

Bakan naa, Ọgbeni Akingbehin ko sai rawọ ẹbẹ fun iranwo awon iyalọja ati babalaje lati fọwọ sowọpọ pẹlu wọn nipa igbogun ti awọn ekute eleyii to n lọ lọwọ ni awon ọja to wa kaakiri tibu-toro Ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi oro re, awon eto ikasẹnilẹ ekute yii lo maa n bẹrẹ ni deede ago bi marun-un irọlẹ (5pm). 

“A sun akoko naa si irọlẹ patapata eleyii ti yoo fun awọn eniyan ni anfaani lati taja wọn laisi idiwọ. A si dupe lọwọ awon eniyan fun atilẹyin wọn.  

Lara awọn ọja ti ẹgbẹ naa tun ti pidan ọwọ wọn nipa sise idajọ iku ojiji fun awọn ekute ni eyi to tun waye ni ọja Suru-Alaba ati Orile-Ifelodun nibi ti ọgọọrọ awọn ekute ti gbe doloogbe lairo tẹlẹ.
Nibayii, ẹgbẹ naa tun fi asiko naa ke si awọn eniyan awujọ lati sa gbogbo ipa wọn lati ri daju wi pe, ekute jina si ayika ati agbegbe won. Won eleyii yoo ran ijọba lọwọ lati tete sẹgun ẹyin iba Lassa to fe maa se bi alagbara lawujo wa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment