Smiley face

Ogun awure to daju

 #ogulutu
Oba ni onibara
Ti ẹ ba jẹ ọlọja tabi oniṣẹ ọwọ, ma rọyin lati maa tẹlẹ awọn alaye mi, eleyii to ṣeeṣe ko gba mi fun oṣu kan tabi ju bẹẹ lọ. Nibi ni maa ti ma tẹnubọ awon ogun awure ajisa to daju, eleyii to le mu okoowo tabi iṣẹ yin gberu koja oye yin. Lọsẹ yii, awọn onibara ni ma fi side.


Awon onibara wa ni ẹmi okoowo wa tabi orisii iṣẹ yoowu ti a le yan laayo. Idi ni yii ti ko fi yẹ ka kọyan wọn kere. Ohun to ṣe pataki ju lọ ni iha tabi iwa wa si awọn onibara wa. Bi onibara wa ba ṣe pọ to bẹẹ ni okoowo wa yoo ṣe fẹju to. Iwa tabi iha wa ti a kọ si onibara wa ni yoo si sọ bi wọn yoo ṣe pọ to lọwọ wa.

Awọn onimọ okoowo ṣe iwadii kan lọdun 2000 lori ohun to le muni padanu onibara.
Awọn idi yii ni awọn onibara ko fi wa mọ: ida kan wọn ṣe alaisi (1%); ida mẹta (3%) won ko kuro ni agbegbe wa; ida mejidinlaadọrin (68%) wọn kọ lati ba wa raja nitori wi pe iwa wa ko tẹ wọn lọrun; nigba ti ida mẹrinla (14%) wọn lọ nitori ọja wa tabi iṣẹ wa ko tẹ wọn lọrun, ida mesan-an (9%) wọn ni wọn ko ba wa raja mọ nitori won ri iru ọja wa nibomii.

Ti ẹ ba wo abajade iwadii yii daadaa, ẹ ri wi pe, eyi to tẹwọn ju nipa idi ti awọn onibara wa ko fi pada wa lati ba wa raja ko ju nipa iwa wa ti ko tẹ wọn lọrun lọ.

Gẹgẹ bi ọlọja, a ni lati ṣọ orisii ede ti a n lo fun awọn onibara wa. Awọn ti wọn ba wa ra ọja gbọdọ jẹ ọrẹ wa. Bakan naa, a ni lati ma ṣe iwadii nipa ohun ti awọn onibara wa n fẹ; awọn ohun ti yoo wu wọn lori ti yoo si mu inu wọn dun.

A gbọdọ ma wa ni imurasilẹ lati yanju isorokisoro ti wọn le gbe pada wa lori ọja ti a n ta fun wọn tabi iṣẹ ti a n ṣe fun wọn. 

Ẹ jẹ ki ọrọ awọn onibara wa jẹ wa logun ju lọ. Ẹ sun mọ wọn nipa oyaya ṣiṣe. Ẹ si ri daju wi pe, o kere tan, ẹ mọ ohun meji tabi mẹta nipa wọn bi orukọ ati nọmba ibanisọrọ wọn.
Awọn onimọ okoowo kan tilẹ ṣe alaye awọn onibara gẹgẹ bi ọba ti ọlọja gbọdọ maa gbe gẹgẹ bi ọba Lamidi.

Lakotan, ẹ maa ṣe awọn ohun ijọloju lẹẹkọọkan tayọ ohun ti won reti lati ọdọ yin. Awon nnkan wọn yii lo le sọ yin di ekurọ lalabaku ẹwa loju awọn onibara yin.

Lẹyin akoko diẹ, awọn eniyan yoo ro boya awure yin lo jẹ, nigba ti ogunlọgọ awọn onibara ba n pe le yin lori bi igba era bo suga.

Olayemi Olatilewa ni orukọ mi, iṣẹ iroyin ni iṣẹ mi, ilu Naijiria si ni ilu ti mo fẹran ju laye, ki Oluwa ko bukun un lọpọlọpọ.  Ire o!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment