Smiley face

Ambode gbe kootu alagbeka wopinle Eko



*Idajo esekese fun awon to ba rufin oju popo
 *Asiko ni yii fun awon olokada ati danfo lati satunse
Kootu alagbeka Ambode
Gomina Akinwunmi Ambode tun gbe ara otun wo ipinle Eko wa pelu bi ijoba re se se ifilole kootu alagbeka lati gbogun ti awon ti won rufin oju popona. Ojo Eti (05/02/16) to koja yii ni ijoba ipinle Eko se ifilole kootu alagbeka naa eleyii ti won pe ni Special Offences Mobile Court ninu ogba ile ejo to gaju lo ti ipinle Eko to kale si Ikeja.

Nibi eto ifilole naa ni komisanna fun eto idajo ti ipinle Eko, Ogbeni  Adeniji Kazeem ti so wi pe, ifilole kootu alagbeka naa je lara eto ijoba Ambode lati feju ona ati tete ri idajo odo gba awon ara ilu ati lati mu asa sise ohun gbogbo letoleto gege bo ti ye kesejari.

"Awon ohun ti a le so wi pe o mu ijoba Ambode ji giri nipa sise iru eto yii ko ju awon olokada ti won feran ki won ma doju ko ona ti moto n gba bo, awon danfo ti won si ilekun won sile lori ere eleyii to mu emi awon eniyan wa ninu ewu. Bakan naa ni awon elese ti won ko biriji sile laigba to je wi pe titi marose ni won feran ati maa sare gba koja. Awon iwa bayii ko fi wa han gege bi awujo to ni asa titele eto gege bi agbekale ilana," Ogbeni Kazeem se alaye naa bee.

Bakan naa ni komisanna tun wi pe, awon awako ti won ba gba oju ona ti kii se ti won bi oju ona BRT naa ni won yoo fika abamo hamu niwaju kootu alagbeka tuntun yii. Koda, komisanna tun menu ba awon soja alagidi to ba rufin oju ona ko ni sai foju wina ofin idajo  niwaju kootu alagbeka.


Gege bi alaye adajo agba fun ipinle eko,  Olufunmilayo Atilade, so ninu alaye tie wi pe, eto tuntun yii yoo mu adiku ba emi awon eniyan ti awon ti ko bikita ofin irinna n seku pa nigbogbo igba. Bakan naa ni onidaju agba Atilade ko sai menu ba isele to seku pa Doyin Serah Fagbenro, eni odun meedogbon (25) ti awako kan seku pa latari iwakuwa oju popona ni agbegbe Lekki-Ajah. O ni ti ko ba si ilana a ti dekun iwa ibaje yii lawujo, ipalara re si awujo yoo tun bo maa lekenka si i ni.

Awon kootu alagbeka yii ni won gbe kale sinu oko bogini nla akero eleyii ti won yoo ma yipo ipinle Eko ka lati se idajo awon arufin oju popo. Adajo majisireeti yoo maa tele awon kootu alagbeka yii pelu awon agbejoro lati Office of the Public Defender (OPD). Awon agbejoro ti won yoo ma  tele kootu yii ni yoo wa fun arufin to ba fe lati be won lowe niwaju adajo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment