Smiley face

Bayii ni a se le se iwosan fun eni to ni kokoro inu eje



Awon ohun elo ti a gbodo wa ni yii:
 
1 Omi osan wewe igo kan tabi oti igo kan tabi omi grape igo kan
2 Capsule red & yellow eyo mewaa (10 pieces)
3 Ewe taba ti won ti lo, sibi imuko kan pere


Bi a se le pese ogun naa ni yii:
Gbogbo nnkan ti a menu ba loke yii ni a maa dapo mo ara won. E le lo osan wewe, oti tabi grape, eyikeyi ninu meteeta ni a le lo. A wa maa tu red and yellow eyo mewaa sinu re. Leyin eyin la ma da ewe taba ti won ti lo, sibi imuko kan sinu re.

Lilo ogun naa
 A ma mu sibi meji laaro ati lale.

Gege bi mo se maa n so ni abala yii, Olayemi Oniroyin kii se onisegun. Ogbon ti awon agba ko mi ni mo ni ki n se alaye re fenikan. Edumare to ni alaafia lodo yoo fi fun gbogbo wa. Ase. Ti e ba lo to ba je fun yin, e je ki n gbo. Ire o!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment