Smiley face

Eko ede Yoruba: YorubaDun 101

Mo ki eyin akekoo kaabo si kilaasi YorubaDun 101. Ni kilaasi yii ni a ti maa ko nipa girama ede Yoruba.

A ko ni je ki idanileko yii gba akoko pupo nipa opolopo oro, lati ma baa je ko su awon akekoo ti won sese n ko nipa ede Yoruba.



Bakan naa, eni anfaani lati bere ibeere, dahun ibeere tabi afikun lori koko ise ti a ba ko. Ohun ti a maa gbe yewo lonii
ni:

Fonetiiki je orisii eko kan eleyii ti o n so nipa iro ede.

O je eko nipa bi a se n pe iro ninu ede Yoruba.

Ninu orisii eko yii kan naa ni a ti n ko nipa awon eya ara ti a n lo fun iro ede pipe ati amulo won boya nipa gbigbo, afipe, ati ero igbalode lilo.

Ona meji ni a le pin awon eya ara ti a n lo fun iro ede pipe si.

1. Afipe-asunsi
2. Afipe-akanmole

Afipe asunsi ni awon eya ara ti won maa n sun soke sodo ti a ba n soro. Isale enu ni a ti ma ri iru eya ara wonyii.

Afipe-akanmole nii awon eya ara ti won ki i kuro ni aaye won. Won maa n wa gbarii ni oju kan ni

Afipe-asunsi
Ete isale
Iwaju ahon
Aarin ahon
Idi eyin ahon
Olele
Eyin isale
Erigi isale

Afipe-akanmole
Ete oke
Erigi okee
Eyin oke
Aja-enu
Afase
Ona ofun
Iho imu mejeeji

ISE AMURELE
1. Nje iwo gba wi pe ipo kan naa ni awon eya ara ti a n lo lati fi gbe iro jade wa?

2. Bi o tile je wi pe oju je eya ara ti a le fi riran, awon Yoruba tun gbagbo wi pe eniyan le fi oju soro. Ipo wo la wa le fi oju
si ni abe fonetiiki?
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment