Smiley face

Olubadan pada wole sun n’Igbo Elerin



*Ajimobo, Ambode, Aregbe ati Amosun bu ola fun Oba Odulana
*Gbogbo oja ni won tipa lojo ti won sin Olubadan
*“Alailabawon oba ile Yoruba ni Odulana”- Buhari
*“Ojulowo omo Olubadan ni emi naa”- Osinbajo
Ayeye isinkun Oba Samuel Odulana
Gbogbo oja nlanla to wa niluu Ibadan pata ni won tipa lojo Eti to koja yii (12/02/16) nigba ti won gbe Oba Samuel Odulana Odugade wonu kaa ile lo. Eleyii ni won se lati fi bu ola fun Olubadan to waja lojo kokandinlogun osu kinni odun yii (19/01/2016). Ninu eto isinku eleyii to waye ni St. Peter’s Cathedra to kale si Aremo, Ibadan ni orisiirisii otokulu ti gbe pejo lati seye ikeyin fun oba to gbese leni odun mokanlelogorun (101).


Lara awon to wa nikale ni gomina ipinle Oyo to tun je olugbalejo agba, Senato Abiola Ajimobi, Gomina Ibikunle Amosun lati ipinle Ogun, Ogbeni Rauf Aregbesola lati ipinle Osun. Bakan naa ni Ogbeni Akinwunmi Ambode lati ipinle Eko ko gbeyin nibi ayeye eto isinku ojo naa.

Awon eniyan ti OLAYEMI ONIROYIN tun kofiri nibi ayeye naa ni minisita fun eto ibanisoro, Ogbeni Bayo Shittu. Gomina ipinle Osun nigba kan ri, Senato Isiaka Adeleke. Bakan naa ni Oloye Harry Akande ati aya gomina ipinle Oyo nigba kan ri naa, Alhaja Mutiat Ladoja, wa lati wa fi ijoko ye Oba Odulana to dologbee si.

Nibi ayeye eto isinku yii,  eleyii ti won ti bere lati ojo kefa osu keji odun yii (06/02/16), ni igbakeji aare orileede Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo ti gbe soju Aare Muhammadu Buhari. Ninu oro Buhari, eleyii ti igbakeji n re jise re, lo ti n se alaye Oba Odulana gege bi oba kan pataki ti ko labawon ni ile kaaro-o-ji-i-re.

“Inu mi dun, mo si tun ri bi anfaani nla lati wa nibi lonii. Ki i se nipa jije asoju fun Aare bi ko se ojuse mi gege bi ojulowo omo Olubadan. A ni lati dupe lowo Oluwa oba mimo wi pe iru eniyan takuatakun bi oba Odulana gba aarin wa koja,” Osinbajo se laye naa bee.
Leyin eto isinku yii ni won gbe oku Oba Odulana lo si Igbo Elerin nibi won ti gbe bi lomo lojo kerinla osu kerin odun 1914 to wa ni ijoba ibile Lagelu. Ibi naa ni won ti feeru fun eeru, ti won si fi erupe fun erupe leyin ti won gbe Oba Odulana wonu kaa ile lo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment