Smiley face

Buhari toro aforijin lowo omo Naijiria latari ina elentiriki to daku


*”Falala ni awon eniyan yoo ma gbadun ina elentiriki lati ose yii lo” - Lai Muhammed
Aare Muhammadu Buhari
Latari ina monamona elentiriki to se monamona lose to koja, eleyii to so gbogbo ilu sinu okunkun birimubirimu ni ijoba apapo, labe akoso Aare Muhammadu Buhari, ti tori aforijin lowo gbogbo ara ilu bayii. Sebi moogun-moote, enikan ki i gunyan ewura ko ma lemo. Ti elebi ba si ti mo ejo re lebi, won ki i pe lori ikunle.


Ikede yii lo jade lati owo Ogbeni Segun Adeyemi to je amugbalegbe fun fun minisita ti n ri si etigbo, ati asa, Alaaji Lai Mohammed.

Ogbeni Adeyemi di ebi isele naa ru awon obayeje kan ti won kolu paipu ti n gbe afefe gaasi, eleyii ti won on lo lati pin ina elentiriki kari gbogbo ilu. Won ni ninu awon ile agbara bi merinlelogun (24) ti ile ise monamona ile yii n lo lati fi tan imole fun ara ilu, metala (13) ni won ri fi sise ninu won lose to koja. Ogbeni  Adeyemi ko sai pe fun iranlowo ara ilu lati fowosowopo nipa gbigbogun ti awon ti won wa isubu orileede yii. 

Bakan naa, ninu atejade to jade lati eka ile ise ijoba eleyii ti Lai Muhammed n dari ni won ti fi da ara ilu loju wi pe, gbogbo atunse to ye ni ijoba Buhari ti se lati mu nnkan pada bosipo. Won si tun fi da ara ilu loju wi pe, lati ose yi lo, falala bi omi ojo ni gbogbo ara ilu yoo maa lo ina elentiriki lo falala.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment