Smiley face

Idanwo Jambu: 250 maaki ko to yan fanda fun olusedanwo mo



Awon omo onidanwo Jambu gba gbogbo oju titi kankan-ankan lose to koja ni agbegbe Maryland to kale siluu Eko Gomina Akinwunmi Ambode nibi won ti n fi ehonu han nipa awon ilana ajo Jambu ti ko te won lorun. Ohun ti awon omo onidanwo naa n tenumo ni wi pe, bawo ni awon yoo se gba aadotalerugba maaki (250) ti awon ko tun ni ni anfaani lati wo ileewe giga to wu won. Eyi tun mo si wi pe, aadotalerugba maaki ko kunwo to lati fi okan olusedanwo bale gege bi esi idanwo.

Bakan naa ni won tun koro oju si segesege ti n waye latari lilo ero komputa lati joko se idanwo naa. Lori eleyii ni ile igbimo asofin agba naa ti n ro ajo naa lati pada si lilo takada ati biro bi ti tele. Won ni lilo ero komputa ko se iranlowo, lopo igba ni ero naa si n gbe omo Oba f’Osun nigba ti esi idanwo ba jade.

Lara ifehonuhan awon olusedanwo jambu yii tun ni wi pe, lopo igba ni ajo yii yoo tun ju awon si awon si ileewe aladani olowo tabua ti awon ko yan rara ni akoko iforukosile.

Ninu iwode ifehonuhan to waye naa ni won ti n pe fun iroloye oga agba ajo naa, Ojogbon Dibu Ojerinde. Koda, won ti gbe ifehonuhan won de ori ero ayelujara twitter pelu oro akole #DibuMustGo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment