Smiley face

Nipinle Ondo, komisanna olopaa tuntun seleri lati segun awon Fulani darandaran




Gomina Mimiko ati Hilda
Arabirin Ibifuro-Harrison Hilda to je komisanna tuntun fun ipinle Ondo ti salaye ninu oro apileso re nikete to wo ilu Akure wi pe, asiko ni yii ti opin yoo de ba awon Fulani darandaran onise ibi ti won ti n yo ipinle naa lenu lati igba yii wa. Ninu oro komisanna to je eleekejidinlogoji (38th) ti yoo je lati igba ti won ti da ipinle Ondo sile lati nnkan bi ogoji odun seyin so wi pe, gbogbo awon elekajeka ti oro naa kan gbongbon ni oun yoo kan si lati ri wi pe, gbogbo erogba oun lati da alaafia pada si ipinle Ondo gunrege. 


Bakan naa ni Arabirin Hilda, omo bibi ipinle Edo, to tun je komisanna obirin ti yoo je sikeji nipinle Ondo, ti fi da gbogbo ara ilu loju wi pe, asiko ti oun de yii, gbogbo ara ilu ni won yoo loju orun pelu ifokanbale. Komisanna olopaa tuntun to tun pe fun ifowosopo ara ilu lo gba ipo lowo ogbeni Mike Ogbodu, eni to n mu ra lati feyinti lenu ise olopaa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment