Smiley face

NIS ti n dogbon lati gba eedegbeta (500) eniyan senu ise nibonkele



Leyin asemase to waye lati eka ile ise ijoba ti n risi wole-wode ti a mo si Nigeria Immigration Service (NIS) to waye lodun 2014. Nibi ti awon eniyan bi ogun ti won wase ti gbe je Olorun nipe laipe ojo. Lori isele yii naa ni Minisita fun eto abele, Aba Moro di ero atimole lori esun jegudujera owo ti awon ti won wa ise naa san.  Wayio, awon eniyan bi eedegbeta ti bere si gbaradi bayii lati wose leka ile ise ijoba naa leyin ti ijoba apapo ti gbegidi eto igbanisise eka ile ise naa.


Lowolowo bayii, ile eko ajo naa to kale si ilu Kano ni iroyin so wi pe, awon eniyan tuntun ti won fe gba sise naa ti n gba idanilekoo saaju ki won to wose. Awon eto ti won se nibonkele yii ni won lo ni i se pelu awon oloselu kan ti won lenu nibe ni ona ati pese ise fun awon eniyan ti won.

Gege bi okan lara awon osise ibudo idanileko yii se so, eni to ko lati daruko ara re, " O je ohun ijoloji bi won se fi awon oruko won sowo siwa lati Abuja lai se wi pe eto igbanisise kan tile waye. Ti eto igbanise ba fe waye, ohun ti gbogbo ara ilu yoo gbo nipa re ni."

“Ati ojo keje osu keta odun yii ni ati pejo silu Kano nibi fun igbaradi. Okan ninu awon oloselu to wa nile igbimo asoju-sofin to wa lati ekun idibo adugbo wa lo fi ise naa ta mi lore. Mo si dupe fun ore ofe ti mo ri gba naa," okan ninu awon ti won on gbaradi nibudo Eko naa se alaye bayii.


Gege bi alaye Arabirin Amina Nqua Habiba Aliyu to je alarina fun ibudo idanileko naa, se alaye wi pe, ko si ohun to jomo bee rara. O tun salaye wi pe, awon ko si nidi eto igbanisise, idanileko awon ti won gba sise lasan ni ise awon. Bakan naa lo tun fi kun wi pe, bi o tile je wi pe, atejade kan lati odo ijoba so nipa igbasise awon egberun marun-un eniyan, o ni sugbon aba yii ko ti wa si imuse.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment