Smiley face

Iriri mi pelu omoge oniparaga 1

Iriri mi pelu omoge oniparaga 1

O sẹburu ọna jade sita gbangba, emi n bọ latoke wa nigba ti oun gba isalẹ bọ wa soke. Ọọkan rere lo si wa, sugbọn ki i sebi ki n ma le sapejuwe bo ti ri. Ọsọrọ omidan ni, yoo si fẹ ga niwọn ẹsẹ bata marun-un tabi ko din diẹ. Opẹlẹngẹ ni, sugbọn pẹlẹngẹ rẹ ko debi igbaaya rẹ. Ohun meji aya rẹ lomi ninu, bẹẹ lo duro kitipi mọ ọ laya bi ẹba Yibo ti won pọn sinu ọra. Awon koro meji ori osan aya rẹ mi sihin-in sọhun-un labẹ asọ bi igba ọmọde meji n ju bọọlu sira won. 


Eyi fi han wi pe ko fi nnkankan ko ẹbun amutorunwa rẹ meji ti mbẹ loke ara. Kosi bi eniyan yoo se woju ọmẹge naa lai gboju losi ibi igbaaya to ta bọkua bi isu Abuja. Bi ẹ ko tilẹ fẹ gboju losi bẹ, awon soja meji ti n pesẹ labẹ asọ ko ni jẹ. Oju ọmọge naa mọ fefe, pupa ara rẹ si la kedere bi igba osumare yọ loju orun. Oun gan-an ni won ba ma pe ni apọn-bepo-rẹ. 

Irun igbalode ti won di ti i gun debadi lo se sori. Bi eniyan ba wo omoge yii latọọkan nibi mo duro si, bi igba eniyan ri angeli ni. Igba to ku die ti yoo de ọdọ mi, mo yabara duro labẹ igi kan ki n le ri akoyinsi rẹ. E ma jẹ n tanyin, bi eniyan ba n wo sinima, bi eni naa ko ba ti wo gẹlẹdẹ ko le mọ adun ti n bẹ ninu iran. 

Mariwo lasan ni mo ri, a se egungun mbẹ lẹyin. Ohun ti omoge yii so mo ibaradi rẹ leyin ri koroboto bi ikoko isebẹ. Sokoto jinsi lo wo, bẹẹ ni gbogbo rẹ le kakaraka bi apo simenti ẹlifanti. Lai fowo kan-an, emi gan-an gba wi pe nnkan ki sẹsẹ rago. Bo se n ri lo ni ikoko eyin re n yi gbiri sotun bẹẹ naa lo yii gbiri sosi. (Ori iya mi ooo!). A fi bi ibadi Kim olokiki ti nbẹ niluu Amerika.

O jo mi loju wi pe iru arewa obirin yii le ma kiri paraga. Bo se n lo ni mo fi okan ro iru ẹgbin to seese ko ma ba pada lowo awon onibara rẹ. Awon omo onimoto ti won o lojuti, won le fọwọ gba ẹgbẹ iya won nidi ka to wa so ọlọmọge to lọjọ iwaju rere to se e mu yangan, akoyinsi re tun jẹ awo-dami-enu.    
Mi o tile mo ohun to mu mi pe ọmọ oniparaga naa pada. Emi ki i mu ogogoro, opa eyin, ale kosi si ninu oro mi. Ki ni mo wa fẹra lọwọ omo oniparaga?

E le ka apa keji NIBI

Iriri mi pelu omoge oniparaga 2
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment