Smiley face

Iriri mi pelu omoge oniparaga 2



Ẹ kaabọ! Ma rọyin lati ka IRIRI MI PẸLU ỌMỌ ONIPARAGA 1 ki ẹ to tesiwaju pẹlu apakeji to jẹ asekagba. Ẹ le ka alaye naa NIBI.
Ti ẹyin ba ti ka a, ẹ jẹ ka tẹsiwaju.
Iriri mi pelu omoge oniparaga 2
O jọ mi loju wi pe iru arẹwa obirin yii le ma kiri paraga. Bo se n lọ ni mo n fi ọkan ro iru ẹgbin to seese ko ma ba pada lọwọ awọn onibara rẹ. Awon ọmọ onimọto ti wọn o lojuti, wọn le fọwọ gba ẹgbẹ iya won nidi ka to wa sọ ọlọmọge to lọjọ iwaju rere to se e mu yangan, akoyinsi rẹ tun jẹ awo-dami-ẹnu.    


Mi o til mọ ohun to mu mi pe ọmọ oniparaga naa pada. Emi ki i mu ogogoro, ọpa ẹyin, ale, kosi si ninu ọrọ mi. Ki ni mo wa fẹ ra lọwọ ọmọ oniparaga?

Igba to sun mọ mi labẹ igi, Mo wi pe, “Sẹ ẹ ni agbo iba?”
Eti asọ abiya rẹ ponkẹkẹ bi epo pupa. Awon eri to so mọ irun abiya rẹ fẹ ẹ le ma jabọ silẹ. “E dakun, ẹ sọ mi kalẹ” Bo se sọrọ yii jade lẹnu rẹ bu tii. Orun ẹnu rẹ dabi igba ti awon ọkọ akodọti ba koja lẹgbẹ ẹni. Ti ehin rẹ ba pọn ko ba tilẹ daa, e wo ni kehin dudu bi ẹni in mu taba. Olorun nikan lo moye ọjọ to ti n wọsọ orun rẹ kiri adugbo, gbogbo rẹ n jafinkan bi ẹyin to ti dobu. Bo se bẹrẹ mọlẹ ti n ba mi tagbo, eti pata funfun to wo han leyin rẹ. Pata funfun to wọ ti pawọda, gbogbo rẹ lo safa seti lọ, bakan naa ni awon idọti dudu so mọ eti pata rẹ lọwọ oke. 

Sasarasa ni gigirise ẹyin ẹsẹ rẹ la bi ẹsẹ mọla. Eekanna ẹsẹ rẹ ati tọwọ ko idọti sinu bi ẹni n sise birisope. Lapalapa ẹyin orun fẹ to osupa oju ọrun. Igba yii ni mo sakiyesi wi pe pupa rẹ ki i se pupa gidi. Gbogbo ẹyin ika ọwọ rẹ jona bi eyin apẹ. Bakan naa ni isalẹ oju re ti pon bi ẹni won sọ lẹsẹ loju. Atike lo n fi n gbera, oju rẹ ti n hunjo bi arugbọ ọgọrun ọdun. Ketekete ni eniyan n wo gbogbo isan ara re to ti di girinni, alawọ ewe, nita labe awọ ara rẹ. Gbogbo bi se n ta agbo fun mi ni i jẹ singọọmu lẹmu pasapasa bi ẹrọ ilọgi. Ete ẹnu rẹ nipọn peeri bi awọ maalu ti won fi n se pọnmọ funfun. 

Kilode ti mo fi pe ọmọ oniparaga gan-an? Iba o kuku se mi, kini mo fe fi agbo iba se? Se ki n se wi pe ogun lọmọ oniparaga fi n taja? Ti ko ba je bẹẹ, bawo ni maa se maa ra ohun ti ko wulo fun mi? Bo se ta fun mi tan sinu ọra, mo fi ọgọrun naira le e lọwọ. Bo se peyin da ni mo sọ agbo rẹ danu sinu igbo. Olorun o ba mi yọ owo mi lapo rẹ. Nitori mi o niidi agbo, kosi ohun ti mo fe fi agbo rẹ se. oju mi tun seesi lọ sibi akoyinsirẹ lọwọ isale, nibi idaji ara, n se ni mo sintọ saarasa, ti mo si gba ibi temi lọ laiwo lẹẹkeji. 

THE END  

Opin sinima lade yii. Mo fe ko ye yin wi pe itan aroko lasan leyi, mi o pade ọmọ oniparaga kankan nibikibi, ki enikeni ma fi oju onisekuse womi (erkk). Sugbọn, ohun kan ti mo n gbiyanju lati fi han yin ni wi pe, ọpọ awon eniyan ti n da wa lọrun lokeere ni ki i se iru eniyan ti yoo wu wa lati sunmo tabi ba sọrẹ ti a ba ni anfaani lati mọ won daada. Aimọye ẹni iyi, ẹni ola lawujọ lo jẹ ika ati apaayan. Aimoye awon eniyan ti won pe ara won ni ẹni Olorun lo je oniwa rirun; ti won si kun fun ọpọlọpọ ẹgbin labẹ asọ.

Emi ma dakẹ nibi na, lati pada si ori ojulowo iroyin gidi. Ninu iroyin tuntun to jade, njẹ ẹyin mọ wi pe, o ti le ni miliọnu mẹta eniyan ti wọn wa sori itakun agbaye Olayemi Oniroyin lati wa ka awon ohun ti a n gbe jade faye ri? Google lo salaye eleyii fun mi ni kedere. To ba je ẹyin lemi ni, Olayemi Oniroyin ni emi o ba fọrọ lọ to ba jẹ ti ipolowo oja ayelujara to munadoko.
Ẹku ikalẹ!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment