Smiley face

Awon koko alaye nipa fáwèlì ede Yorùbá

Fáwèlì ni ìró tí a pè tí kò sí ìdiwó fún aféfé tàbí èémí to n ti inu edo foro bo wa si ona enu.

Bí àpeere: a, e, e, i, o, o, u, an, en, in, on, un,.

Gbogbo ìró fáwèlì èdè Yorùbá ló je ìró akùnyùn.

Èyí ni pé tán-án-ná gbòn rìrì nígbà tí a pè wón.

Orísi méjì ni fáwèlì èdè Yorùbá, àwon ìsòrí méjì náà ni…Fáwèlì àìránmúpè àti fáwèlì àránmúpè....

Arabirin Adebisi Mujidat Adeshina to je onimo olukoni gbe ibeere jade lori ikanni Yoruba Dun ori Facebook nipa iye ona ti fáwèlì ede Yoruba pin si. Bakan ni won tun se idahun naa pelu awon alaye to kesejari.

Alaye won naa ni yii:

"Gege bi a ti se n ba idahun wa bo lori faweli ede Yoruba, mo so wipe ona meji ni o pin si

1. Faweli Airanmupe(oral vowel)A, E, E, I, O, O, U bi apeere; Aja, Ede, Eja, Igi, Oju, Obe.

Leta "U" ki i bere oro ninu ede Yoruba afi eka ede/ede adugbo.

Ijebu ati Ife a maa fi leta U bere oro. Apeere Ule, Usu abbl.

2. Faweli Aranmupe (nazal vowel) An, En, In, On, Un. Apeere; erAN, igUN, igbIN, ibON. abbl."
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment