Smiley face

Imo girama ede geesi ni Yoruba: "Who" ati "Whom" (1)

Ninu ede geesi, lopo igba ni awon eniyan maa n se iye meji boya "whom" lo ye kan lo ni abi "who"ni awon aye kan ninu iseda gbolohun.

Maa gbiyanju lati se alaye lori ona meji ti a le gba kogoja nigba ti a ba fe se amulo awon oro wonyi ninu gbolohun ede geesi.


E je ki n koko bere pelu ona to ya julo tabu ona abuja to ya kanmokanmo lati mo bi a se le lo awon oro naa.

Nipa mimo boya "whom" lo ye lati lo ni abi "who", a le fi he/him se odinwo re eleyii ti yoo tanna imole si oye wa.

He duro fun =Who
Him duro fun =Whom

E je ka wo apeere yii:

"Who /Whom" wrote the letter?

Lati mo boya "who" ni ka lo tabi "whom" ni ka lo, e je ka fi he/him ropo won lati mo ohun to ye.
Eyikeyi to ba ti ni itunmo gidi ni yoo je ka mo inu odo ta a dorunla si.

"He" wrote the letter.
E ri wi pe "He" lo ni itunmo pelu agbekale gbolohun naa.
Fun idi eyi,"who" ni yoo duro nibe ki i se "whom"

Apeere Keji:
Who/Whom should I vote for?

E ri wi pe "he" ko dan moran pelu gbolohun oke yii nigba ti a ba fi se odinwon re.
Should I vote for him?

Sugbon ti a ba fi "him" si, e ri wi pe o gbe itunmo gidi jade.
Iyato kan to foju han to ye ka kiyesi ni ipo ti a gbe "him"si.

Ninu girama ede geesi,"He" je aropo oro oruko nipo oluwa (subject) nigba ti "him" je aropo oro oruko ni ipo abo (object).

Idi ni yii ti "Him" ko fi le duro si ipo "He".
Sugbon eyi gan-an ko ni koko alaye wa bikose lati lo won ni ona ti yoo fi fun wa loye bi a se le lo "who" ati "whom" nigba ti a ba fe seda gbolohun.

Apeere Keta:
We all know who/whom pulled that prank.
Ninu Apeere oke yii, orisii odin-indi gbolohun meji ni won lepo: we all know ati who/whom pulled that prank.

Sugbon abala keji gbolohun yii nise ti a wa fe se wa, eleyii ti a ti fe mo boya who tabi whom lo ye.
He pulled that prank.

Ti a ba lo "He" lati fi sodiwon gbolohun naa, a o ri wi pe o danmoran.
Fun idi eyi,"who" lo ye lati lo ninu gbolohun naa.
We all know who pulled that prank.

E je ka tu wo apeere kerin:
We wondered who/whom the book was about.

A o ri wi pe onibeji naa tu ni gbolohun yii: we wondered ati who/whom the book was about.
Sugbon abala keji nise wa bi ti isaaju nitori ibe ni who/whom wa.
Ti a ba lo "he", ko mu itunmo gidi jade. Sugbon, e je ka gbiyanju "him"
The book was about him.

E ri wi pe eleyii fun wa ni itumo to fidi mule. Fun idi eyi, "whom" lo pegede lati lo ninu gbolohun naa.

Se e ko gbagbe wi pe ona meji ni mo se ileri lati gbe alaye mi le, lori ona lati mo bi e se lelo Who/Whom ninu gbolohun ede geesi.

Ona kinni ni yii, ma maa se alaye ona keji laipe.
Sugbon inu mi yoo dun lati gba afikun ati ero yin nipa eyi.

E se.





































Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment