Smiley face

Ayederu Pásítò̩ ń jé̩jó̩ ló̩wó̩ ní kó̩ò̩tù lé̩yìn tí ó fún ìyá àti o̩mo̩ lóyún.

Oladeji Kehinde


Kí ó tó di àkókò yìí, ìròyìn ti jáde ni o̩dún tí ó ko̩já nípa o̩kùnrin kan tí o pe ara rè̩ ní ojís̩é̩ o̩ló̩run tí ó fún ogún nínú àwo̩n o̩mo̩ ìjo̩ rè̩ lóyún.

O̩kùnrin e̩ni o̩dún mé̩ta-le-l'àádó̩ta (53) náà tí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Timothy Agwu ní ó so̩ wípé è̩mí-mímó̩ ní ó darí òun láti máa fún àwo̩n o̩mo̩ ìjo̩ náà lóyún lé̩yo̩kànkan, às̩e olúwa náà l'òun sì ń tè̩lé.

Púpò̩ nínú àwo̩n tí ó gbóyún sí níkù yìí ni ó jé̩ ìyàwó ilé àti ò̩s̩ó̩ró̩ o̩ló̩moge. Gbogbo èyí ni ó s̩e̩lè̩ ní o̩dún tí ó ko̩já.

O̩ló̩tò̩ ní tòun ò̩tò̩. Gé̩gé̩ bí e̩ sì ti mò̩ wípé àrà kìí tán ní ilé alárà. Pásítò̩Timothy tún ti padà sí ojú ìwé ìròyín báyìí ó, ló̩tè̩ yìí pè̩lú òun àrà ò̩tún ni.

Ìròyìn tí ó ń lo̩ ló̩wó̩ báyìí ni wípé ò̩gbé̩ni yìí ń jéjó̩ ló̩wó̩ báyìí ní kóòtù Enugu nígbà tí ìyàwó ré̩, Veronica Ngwu, wó̩ o̩ lo̩ ilé e̩jó̩ lórí è̩sùn wípé ó fún arábìrin kan àti o̩mo̩ rè̩ ní oyún.

Arábìrin ò̩hún tí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Calista Omeje tí o jé̩ o̩mo̩ ìjo̩ pásítò̩ yìí àmó̩ tí ó ti di ìyàwó ilé rè̩ báyìí só wipé "o̩ko̩ mi ni ó mú mi dé ò̩dò̩ pásítò̩ Timothy láti lo̩ gbó̩ ìran tí ó rí sí mi.

Bí ó ti di wípé o̩wó̩ wo̩wó̩ tí e̩sè̩ sì wo̩ e̩sè̩ nìye̩n tí gbogbo wa sì di o̩mo̩ ìjo̩ rè̩, ìye̩n God's Favor Ministry, Nsukka".

Ó tè̩síwájú nínú ò̩rò̩ rè̩ fún ilé e̩jó nígbà tí ó so̩ wípé "oko̩ mi tí mo bí bí o̩mo̩ mé̩wàá fún ti fi ìjo̩ náà sílè̩ àmo̩ èmi ò tè̩le, àti wípé mo tilè̩ ti bímo̩ kan rí fún pásítò̩ àmó̩ tí o̩mo̩ náà saláìsí".

Calista tún wá so̩ wípé o̩ko̩ òun mò̩ nípá bí o̩mo̩ àwo̩n obìnrin s̩e di ìyàwó ló̩dè̩dè̩ pásítò̩ tí àwo̩n méjèjì dè̩ ti finú s̩onú báyìí.


Ilé-e̩jó̩ májísírétì apá àríwá Enugu ti ìgbé̩jó̩ náà ti ń wáyé ti wá sún ìgbé̩jó̩ di o̩jó̩ ke̩rìndínló̩gbò̩n osù ke̩sàn-án o̩dún yìí. 

Timothy Ngwu tí ò̩rò̩ kàn gan ò sí ní kóòtù ló̩jó̩ ajé (Monday) tí ìgbé̩jó̩ wáyé, ìròyin tí a gbó̩ ni wípé ó ń gba ìtó̩jú ló̩wó̩ ní ilé-ìwòsàn kan ní Enugu









Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment