Smiley face

Òs̩ìs̩é̩ NDLEA rì sómi ní ìgbìyànju láti mú ò̩daràn

Kehinde Oladeji

Ò̩kan lára àwo̩n òs̩ìs̩é̩ ààjo̩ tí ń gbógun ti gbígbé òògùn olóró ti ìpínlè̩ Borno ti pàdánù è̩mí rè̩ nígbà tí ó ń gbìyànjú àti mú ògbóǹtarìgì olóògùn olóró kan.

Adárí ààjo̩ náà ni ó fi ò̩rò̩ ò̩hún tó àwo̩n oníròyìn létí ní o̩jó̩ ajé. Ìs̩è̩lè̩ yìí ni ó wáyé ní agbègbè Gwaange, Maiduguri nígbà ti òs̩ìs̩é̩ NDLEA mé̩rin kán sí agbami ní ète àti mú e̩ni afurasí olóògùn olóro kan tí wó̩n sì rì torí wo̩n ò mò̩wè̩. 

Mé̩ta nínú móríbó̩ nínú ìs̩è̩lè̩ náà àmó̩ gbogbo ìgbìyànjú àti ra è̩mi e̩nì ke̩rin padà ni ó já sí asán nígbà tí ó kú sí ilé ìwòsàn. Ààjo̩ NDLEA ti so̩ wípé ìs̩è̩lè̩ yìí ò ní dá àwo̩n ló̩wó̩ kó̩ torí àwo̩n yóò ri wípé o̩wó̩ bá afurasí náà.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment