Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (23)

#AyeOlabisiK23

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada 
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (23)
Mo ro wi pe ki ni mo le se. Mo ranti ago ibanisoro mi ti o ti wa ni pipa lati igba ti awon okunrin meji oloriburuku un ti gba lowo mi. Mo sure wa gburugburu lori beedi, mi o ri nibe. Abi oga yii ti pada mu ago yii lo ni?



A se o ti jabọ sẹgbẹ beedi lodi keji lohun ni. Mo pada ri nibi to jabo si, nibi ẹsẹ beedi. Bi mo se tan lo muna wa, ago naa seju lebelebe. O sese n gbera so ni. Igba to ya ni ina re mole kedere, eleyii to fihan wi pe o ti tan tan. Ki n to gbiyanju ati te ohunkohun, atẹjise bi mefa lo sare wole leekan naa.



Mo ri ti oko mi, ati ti ore oko mi. Mo ro wi pe igba ti ore oko ko mo ibi ti won gbe mi lo, lo mu pe oko mi. Awon oloribuku si ti gba foonu lowo mi ni gbogbo igba yii. Boya igba ti oko afesona mi naa gbiyanju titi ti ko ri mi ba soro lo je ko fi atẹjise sori ago mi.



Mo mọ lokan mi wi pe ore oko afesona mi o ti daamu ju bo ti ye lo. A ti wi pe inu aibalẹ okan ni yoo wa. Nomba tie ni mo sare pe.



‘Hello, ibo lowo ataaro ni mo ti n try number ẹ. Se Alafia lo wa sa?’

Pelu itara ati iberu ni ore oko mi fi n soro lodi keji loun. Mi o tile mo ohun ti mo le so fun gege bi esi oro re. N se ni mo bu sekun peregede.



“ Kilose e, ba mi soro now. Ibo lo wa bayii? Ba mi soro se?”

Bi ti n soro lo n re mi lekun, bee ni omi n jade loju mi poroporo. Mi o tile mo bi mo se fe fi enu soro wi pe oga oloribuku yen ti pada fi tipatipa ba mi sun.



“ Alafia ni mo wa”. Mo pada soro leyin ekun mi.



Mo wi fun wi pe alafia ni mo wa sugbon ko ma bo wa ba mi nibi ti mo wa. O beere ibi ti mo wa gan-an, sugbon emi gan-an o le so pato ibi ti mo wa. 

O ni se mo le ri eniyan kan bi, ti mo ba ti mo ibi ti mo wa, mo le pe oun pada ki oun le tete ma a bo wa ba mi. Mo se ileri fun wi pe maa gbiyanju, mo si pa ago mi.



Mo gbe ago kale, mo ri telifoonu iletura lori tabili, eleyi ti won fi ma n pe awon osise ti eniyan ba fe ounje tabi ohun kan. Nomba ti eniyan o pe wa lori tabili legbe foonu alasomolẹ naa.



“Hello, e jowo ki ni mi le se fun yin.” Ohun obirin ni ohun ti mo gbo. O si mu inu mi dun, tori obinrin lo le se iru iranwo ti mo fe.



“E jowo anti, mo niidi iranlowo yin”



“Ok, ko si wahala. Ki ni mi le se fun yin gan-an”



“E jowo, mo fe ki e yoju si mi ni, e jowo, e ma binu”



“Ko si wahala, enikan ma wa ba yin”



“Enikan ke? Eyin gan-an gan-an ni mo fe. E jowo, e ma binu. E jowo, e yoju si mi.”



“Ko si wahala, kini nomba yara yin”



“Nomba yara mi?” Mo gboju wo eyin, lara kokoro enu ona. Keyholder nla ti won so kokoro mo, ara re ni nomba yara ti mo wa wa: “ Nomba 021”



“Ok, mi bo wa ba yin”



Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment