Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K 28



#AyeOlabisiK28

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K 28
Sii Olootu,

Mo ki yin wi pe e ku ojo meta. Mo fe rawo ẹbẹ mi si gbogbo ololufẹẹ Yoruba Dun fun idaduro ọlọjọ pipe to de ba leta mi. E fori ji mi. Ki i ku se wi pe mo ti ni awon leta mi yii nile tele, mo kan an gbiyanju lati ma ko won diẹdiẹ ki n si maa fi ranse naa ni.


O wu mi ki n ti seri pada lati igba yii wa, sugbon aye ni ko si fun mi. Bi o tile je wi pe ohun ti mo n la koja lowolowo bayii ye awon Olootu, sugbon dandan ni fun mi lati toro aforijin lowo eyin ololufẹẹ mi.

Ko ba wu mi ki n se alaye awon idi pataki to fa idiwo fun mi, sugbon awon Yoruba ni gbogbo aso ko ni a n sa loorun. A ti wi pe okookan la yose leku. Nitori idi eyi, e dakun, ori ikunle ni mo wa.


Mo fe fi dayin loju wi pe mo ti fi leta mi ranse si Olootu. Eleyii ti o je itesiwaju ibi ti mo ba leta mi to kehin de. Sugbon Olootu gba mi ni imoran lati ko eleyii ti mo n ko yii saaju ki won to se atejade leta mi tuntun naa. 

Idi pataki si ni wi pe, won ni aimoye eniyan ni o ti darapo mo Yoruba Dun eleyii ti won ko tile mo mi rara.

Bakan naa, awon ti won tile mo mi, pipẹ ti leta mii pe le je ki won gbagbe ibi ti itan mi ti bẹrẹ. E mi naa si ro wi pe ti mo ba kọ lati carry awon eniyan mi along, mo so erogba kiko leta mi nu. Eleyii to je lati je ki awon eniyan ri ogbon kan tabi meji ko ninu itan aye mi.


Fun idi eyi, mo ki gbogbo eyin ti e n ka leta mi fun igba akoko. Oruko mi ni Olabisi K. Ile olorogun ni ati bi mi, baba mi si ti se alaisi. Igba ti baba mi ku, awon ebi gbe ogun dide nitori iya mi ni iyawo to kere ju. Omo meji pere si ni iya mi bi fun baba mi, emi obinrin ati aburo mi okunrin. 

Iya mi tiraka fun mi ki n le kawe  gboye akoko ni ile eko giga. Olorun ba mi se, kete ti mo pari ni mo rise. Idi ise yii ni ogun ti dide si mi. Oga kan ti won gbe wa si ibi ise mi lo ni oun fe ba mi sun ni tipatipa. Mo ko jale, sugbon leyinoreyin ohun meta lo sele si mi eleyii to je ibanuje ati ogbe okan fun mi.

* Oga yii pada ba mi sun.

*O da mi duro lenu ise.

*Bakan naa lo tun paro mo mi wi pe mo ji eru ile ise pamo. O si setan ati je mi niya nipa riran mi lo sewon.

Eyin eniyan mi, di endi lo pin sinima. Bi ko ba ti pari, njẹ eyin mo wi pe ko ti i le pari? Kilosele ni ikeyin ohun gbogbo? Awon Yoruba ni, to ba ku die ki omo oloore jin si koto, won ni monamona a se ise imole. Se monamona ohun pada tan a bi ko tan? Sebi won ni bi oko ko jina, ila ki i ko. Eyin e saa ma ba mi bo, nitori won ni eni ba lo, lo ba ku. A wa ko ni ku ni ase Eledumare.

Emi ni tiyin ni tooto.

Olabisi K.

 Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment